NIGBATI o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila si ọdọ, o fi agbara fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́, lati ma lé wọn jade ati lati ṣe iwòsan gbogbo àrun ati gbogbo aisan. Orukọ awọn aposteli mejila na ni wọnyi: Eyi ekini ni Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀; Filippi, ati Bartolomeu; Tomasi, ati Matiu ti iṣe agbowode; Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Lebbeu, ẹniti a si npè ni Taddeu; Simoni ara Kana, ati Judasi Iskariotu, ẹniti o fi i hàn. Awọn mejejila wọnyi ni Jesu rán lọ, o si paṣẹ fun wọn pe, Ẹ máṣe lọ si ọ̀na awọn keferi, ẹ má si ṣe wọ̀ ilu awọn ará Samaria
Kà Mat 10
Feti si Mat 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 10:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò