SA kiye si i, ọjọ na mbọ̀, ti yio ma jó bi iná ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yio dabi akékù koriko: ọjọ na ti mbọ̀ yio si jo wọn run, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti kì yio fi kù gbòngbo tabi ẹka fun wọn. Ṣugbọn Õrùn ododo yio là, ti on ti imularada ni iyẹ́-apá rẹ̀, fun ẹnyin ti o bẹ̀ru orukọ mi; ẹnyin o si jade lọ, ẹnyin o si ma dagba bi awọn ẹgbọrọ malu inu agbo. Ẹnyin o si tẹ̀ awọn enia buburu mọlẹ: nitori nwọn o jasi ẽrú labẹ atẹlẹsẹ̀ nyin, li ọjọ na ti emi o dá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Kà Mal 4
Feti si Mal 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mal 4:1-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò