KIYESI i, Emi o rán onṣẹ mi, yio si tún ọ̀na ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio de li ojijì si tempili rẹ̀, ani onṣẹ majẹmu na, ti inu nyin dùn si; kiye si i, o mbọ̀ wá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn tali o le gbà ọjọ wíwa rẹ̀? tani yio si duro nigbati o ba fi ara hàn? nitori on dabi iná ẹniti ndà fadakà, ati bi ọṣẹ afọṣọ: On o si joko bi ẹniti nyọ́, ti o si ndà fadakà: yio si ṣe awọn ọmọ Lefi mọ́, yio si yọ́ wọn bi wurà on fadakà, ki nwọn ki o le mu ọrẹ ododo wá fun Oluwa. Nigbana ni ọrẹ Juda ati ti Jerusalemu yio wù Oluwa, gẹgẹ bi ti ọjọ igbãni, ati gẹgẹ bi ọdun atijọ. Emi o si sunmọ nyin fun idajọ, emi o si ṣe ẹlẹri yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura eké, ati awọn ti o ni alagbaṣe lara ninu ọyà rẹ̀, ati opo, ati alainibaba, ati si ẹniti o nrẹ́ alejo jẹ, ti nwọn kò si bẹ̀ru mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Kà Mal 3
Feti si Mal 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mal 3:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò