Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọla mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀ru mi ha da? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin: Ẹnyin alufa, ti ngàn orukọ mi. Ẹnyin si wipe, Ninu kini awa fi kẹ́gàn orukọ rẹ?
Ẹnyin fi akarà aimọ́ rubọ lori pẹpẹ mi; ẹnyin si wipe, Ninu kini awa ti sọ ọ di aimọ́? Ninu eyi ti ẹnyin wipe, Tabili Oluwa di ohun ẹgàn.
Bi ẹnyin ba si fi eyi ti oju rẹ̀ fọ́ rubọ, ibi kọ́ eyini? bi ẹnyin ba si fi amúkun ati olokunrùn rubọ, ibi kọ́ eyini? mu u tọ bãlẹ rẹ lọ nisisiyi; inu rẹ̀ yio ha dùn si ọ, tabi yio ha kà ọ si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ bẹ̀ Ọlọrun ki o ba le ṣe ojurere si wa: lati ọwọ nyin li eyi ti wá: on o ha kà nyin si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Ta si ni ninu nyin ti yio se ilẹkun? bẹ̃li ẹnyin kò da iná asan lori pẹpẹ mi mọ. Emi kò ni inu-didùn si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, bẹ̃li emi kì yio gba ọrẹ kan lọwọ nyin.
Nitori lati ilã-õrùn titi o si fi de iwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yio tobi lãrin awọn keferi; nibi gbogbo li a o si fi turàri jona si orukọ mi, pẹlu ọrẹ mimọ́: nitori orukọ mi o tobi lãrin awọn keferi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Nitori ẹnyin ti sọ ọ di aimọ́, ninu eyi ti ẹ wipe, Tabili Oluwa di aimọ́; ati eso rẹ̀, ani onjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gan.
Ẹnyin wi pẹlu pe, Wo o agara kili eyi! ẹnyin ṣitìmú si i, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; ẹnyin si mu eyi ti o ya, ati arọ, ati olokunrùn wá; bayi li ẹnyin mu ọrẹ wá: emi o ha gbà eyi lọwọ nyin? li Oluwa wi.
Ṣugbọn ifibu ni fun ẹlẹtàn na, ti o ni akọ ninu ọwọ́-ẹran rẹ̀, ti o si ṣe ileri ti o si fi ohun abùku rubọ si Oluwa; nitori Ọba nla li emi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ẹ̀ru si li orukọ mi lãrin awọn keferi.