O si ṣe, ni ijọ keji, nigbati nwọn sọkalẹ lati ori òke wá, ọ̀pọ awọn enia wá ipade rẹ̀.
Si kiyesi i, ọkunrin kan ninu ijọ kigbe soke, wipe, Olukọni, mo bẹ̀ ọ, wò ọmọ mi; nitori ọmọ mi kanṣoṣo na ni.
Si kiyesi i, ẹmi èṣu a ma mu u, a si ma kigbe lojijì; a si ma nà a tàntàn titi yio fi yọ ifofó li ẹnu, a ma pa a lara, a tilẹ fẹrẹ má fi i silẹ lọ.
Mo si bẹ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ lati lé e jade; nwọn kò si le ṣe e.
Jesu si dahùn, wipe, Iran alaigbagbọ́ ati arekereke, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti ṣe sũru fun nyin pẹ to? Fà ọmọ rẹ wá nihinyi.
Bi o si ti mbọ̀, ẹmi èṣu na gbé e ṣanlẹ, o si nà a tantan. Jesu si ba ẹmi aimọ́ na wi, o si mu ọmọ na larada, o si fà a le baba rẹ̀ lọwọ.
Ẹnu si yà gbogbo wọn si iṣẹ ọlánla Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati hà si nṣe gbogbo wọn si ohun gbogbo ti Jesu ṣe, o wi fun awon ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe:
Ẹ jẹ ki ọrọ wọnyi ki o rì si nyin li etí: nitori a o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ.
Ṣugbọn ọ̀rọ na ko yé wọn, o si ṣú wọn li oju, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ ọ: ẹ̀ru si mba wọn lati bère idi ọ̀rọ na.
Iyan kan si dide lãrin wọn, niti ẹniti yio ṣe olori ninu wọn.
Nigbati Jesu si mọ̀ ìro ọkàn wọn, o mu ọmọde kan, o gbé e joko lọdọ rẹ̀,
O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba gbà ọmọde yi nitori orukọ mi, o gbà mi: ati ẹnikẹni ti o ba gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi: nitori ẹniti o ba kere ju ninu gbogbo nyin, on na ni yio pọ̀.
Johanu si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, awa ri ẹnikan o nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade; awa si da a lẹkun, nitoriti kò ba wa tọ̀ ọ lẹhin.
Jesu si wi fun u pe, Máṣe da a lẹkun mọ́: nitori ẹniti kò ba lodi si wa, o wà fun wa.
O si ṣe, nigbati ọjọ atigbà soke rẹ̀ pé, o gbé oju le gangan lati lọ si Jerusalemu.
O si rán awọn onṣẹ lọ si iwaju rẹ̀: nigbati nwọn si lọ nwọn wọ̀ iletò kan ti iṣe ti ara Samaria lọ ipèse silẹ dè e.
Nwọn kò si gbà a, nitoriti oju rẹ̀ dabi ẹnipe o nlọ si Jerusalemu.
Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ Jakọbu on Johanu si ri i, nwọn ni, Oluwa, iwọ ko jẹ ki awa ki o pè iná lati ọrun wá, ki a sun wọn lúlu, bi Elijah ti ṣe?
Ṣugbọn Jesu yipada, o si ba wọn wi, o ni, Ẹnyin kò mọ̀ irú ẹmí ti mbẹ ninu nyin.
Nitori Ọmọ-enia ko wá lati pa ẹmi enia run, bikoṣe lati gbà a là. Nwọn si lọ si iletò miran.
O si ṣe, bi nwọn ti nlọ li ọ̀na, ọkunrin kan wi fun u pe, Oluwa, Emi nfẹ lati ma tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ ba nlọ.
Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio fi ori rẹ̀ le.
O si wi fun ẹlomiran pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn o wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinku baba mi na.
Jesu si wi fun u pe, Jẹ́ ki awọn okú ki o mã sinkú ara wọn: ṣugbọn iwọ lọ ki o si mã wãsu ijọba Ọlọrun.
Ẹlomiran si wi fun u pe, Oluwa, emi nfẹ lati mã tọ̀ ọ lẹhin; ṣugbọn jẹ ki emi ki o pada lọ idagbere fun awọn ara ile mi.
Jesu si wi fun u pe, Kò si ẹni, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ le ohun-elo itulẹ, ti o si wò ẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun.