Luk 8:4-15

Luk 8:4-15 YBCV

Nigbati ọ̀pọ ijọ enia pejọ pọ̀, lati ilu gbogbo si tọ̀ ọ wá, o fi owe ba wọn sọ̀rọ pe: Afunrugbin kan jade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na; a si tẹ̀ ẹ mọlẹ, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ṣà a jẹ. Omiran si bọ́ sori apata; bi o si ti hù jade, o gbẹ nitoriti kò ni irinlẹ omi. Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa. Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn. Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun. Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là. Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin. Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo. Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa