Nigbati o si gbé oju rẹ̀ soke si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o ni, Alabukun-fun li ẹnyin òtoṣi: nitori ti nyin ni ijọba Ọlọrun.
Alabukun-fun li ẹnyin ti ebi npa nisisiyi: nitoriti ẹ ó yo. Alabukun-fun li ẹnyin ti nsọkun nisisiyi: nitoriti ẹnyin ó rẹrin.
Alabukun-fun li ẹnyin, nigbati awọn enia ba korira nyin, ti nwọn ba yà nyin kuro ninu ẹgbẹ wọn, ti nwọn ba gàn nyin, ti nwọn ba ta orukọ nyin nù bi ohun buburu, nitori Ọmọ-enia.
Ki ẹnyin ki o yọ̀ ni ijọ na, ki ẹnyin ki o si fò soke fun ayọ̀: sá wò o, ère nyin pọ̀ li ọrun: nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn woli.
Ṣugbọn egbé ni fun ẹnyin ọlọrọ̀! nitoriti ẹnyin ti ri irọra nyin na.
Egbé ni fun ẹnyin ti o yó! nitoriti ebi yio pa nyin. Egbé ni fun ẹnyin ti nrẹrin nisisiyi! nitoriti ẹnyin o gbàwẹ, ẹnyin o si sọkun.
Egbé ni fun nyin, nigbati gbogbo enia ba nsọrọ nyin ni rere! nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn eke woli.
Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin.
Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin.
Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu.
Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère.
Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu.
Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn.
Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ.
Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada.
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.
Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.