Luk 6

6
Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà Ní Ọjọ́ Ìsinmi
(Mat 12:1-8; Mak 2:23-28)
1O si ṣe li ọjọ isimi keji lẹhin ekini, Jesu kọja larin oko ọkà; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si nya ipẹ́ ọkà, nwọn nfi ọwọ́ ra a jẹ.
2Awọn kan ninu awọn Farisi si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi?
3Jesu si da wọn li ohùn, wipe, Ẹnyin kò kawe to bi eyi, bi Dafidi ti ṣe, nigbati ebi npa on tikararẹ̀ ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀;
4 Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si mu akara ifihàn ti o jẹ, ti o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu; ti kò yẹ fun u lati jẹ, bikoṣe fun awọn alufa nikanṣoṣo?
5O si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi.
Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ
(Mat 12:9-14; Mak 3:1-6)
6O si ṣe li ọjọ isimi miran, ti o wọ̀ inu sinagogu lọ, o si nkọ́ni: ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ọtún rọ.
7Ati awọn akọwe ati awọn Farisi nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le ri ọna ati fi i sùn.
8Ṣugbọn o mọ̀ ìro inu wọn, o si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, ki o si duro lãrin. O si dide duro.
9Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Emi o bi nyin lẽre ohunkan; O tọ́ lati mã ṣe ore li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run?
10Nigbati o si wò gbogbo wọn yiká, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si ṣe bẹ̃: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.
11Nwọn si kún fun ibinu gbigbona; nwọn si ba ara wọn rò ohun ti awọn iba ṣe si Jesu.
Jesu Yan Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Mejila
(Mat 10:1-4; Mak 3:13-19)
12O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun.
13Nigbati ilẹ si mọ́, o pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ninu wọn li o si yàn mejila, ti o si sọ ni Aposteli;
14Simoni, (ẹniti o si sọ ni Peteru,) ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filippi ati Bartolomeu,
15Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,
16Ati Juda arakunrin Jakọbu, ati Judasi Iskariotu ti iṣe onikupani.
Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn
(Mat 4:23-25)
17O si ba wọn sọkalẹ, o si duro ni pẹ̀tẹlẹ, pẹlu ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ ijọ enia, lati gbogbo Judea, ati Jerusalemu, ati àgbegbe Tire on Sidoni, ti nwọn wá lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara kuro ninu arùn wọn;
18Ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si mu wọn larada.
19Gbogbo ijọ enia si nfẹ fi ọwọ́ kàn a; nitoriti aṣẹ njade lara rẹ̀, o si mu gbogbo wọn larada.
Ìre ati Ègún
(Mat 5:1-12)
20Nigbati o si gbé oju rẹ̀ soke si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o ni, Alabukun-fun li ẹnyin òtoṣi: nitori ti nyin ni ijọba Ọlọrun.
21 Alabukun-fun li ẹnyin ti ebi npa nisisiyi: nitoriti ẹ ó yo. Alabukun-fun li ẹnyin ti nsọkun nisisiyi: nitoriti ẹnyin ó rẹrin.
22 Alabukun-fun li ẹnyin, nigbati awọn enia ba korira nyin, ti nwọn ba yà nyin kuro ninu ẹgbẹ wọn, ti nwọn ba gàn nyin, ti nwọn ba ta orukọ nyin nù bi ohun buburu, nitori Ọmọ-enia.
23 Ki ẹnyin ki o yọ̀ ni ijọ na, ki ẹnyin ki o si fò soke fun ayọ̀: sá wò o, ère nyin pọ̀ li ọrun: nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn woli.
24 Ṣugbọn egbé ni fun ẹnyin ọlọrọ̀! nitoriti ẹnyin ti ri irọra nyin na.
25 Egbé ni fun ẹnyin ti o yó! nitoriti ebi yio pa nyin. Egbé ni fun ẹnyin ti nrẹrin nisisiyi! nitoriti ẹnyin o gbàwẹ, ẹnyin o si sọkun.
26 Egbé ni fun nyin, nigbati gbogbo enia ba nsọrọ nyin ni rere! nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn eke woli.
Ẹ Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Yín
(Mat 5:38-48; 7:12a)
27 Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin.
28 Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin.
29 Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu.
30 Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère.
31 Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu.
32 Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn.
33 Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ.
34 Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada.
35 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.
36 Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.
Ọ̀rọ̀ Nípa Ṣíṣe Ìdájọ́
(Mat 7:1-5)
37 Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin:
38 Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin.
39O si pa owe kan fun wọn, Afọju le ṣe amọ̀na afọju? awọn mejeji kì yio ṣubu sinu ihò?
40 Ẹniti a nkọ́ ki ijù olukọ́ rẹ̀ lọ: ṣugbọn olukuluku ẹniti o ba pé, yio dabi olukọ́ rẹ̀.
41 Ẽṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ?
42 Tabi iwọ o ti ṣe le wi fun arakunrin rẹ pe, Arakunrin, jẹ ki emi ki o yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, nigbati iwọ tikararẹ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? iwọ agabagebe, tètekọ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi kuro ti mbẹ li oju arakunrin rẹ.
Igi ati Èso Rẹ̀
(Mat 7:16-20; 12:33-35)
43 Nitori igi rere kì iso eso buburu; bẹ̃ni igi buburu kì iso eso rere.
44 Olukuluku igi li a ifi eso rẹ̀ mọ̀; nitori lori ẹgún oṣuṣu, enia kì iká eso ọpọtọ bẹ̃ni lori ẹgún ọgàn a kì iká eso ajara.
45 Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá; ati enia buburu lati inu iṣura buburu ọkàn rẹ̀ ni imu ohun buburu jade wá: nitori lati ọ̀pọlọpọ ohun ọkàn li ẹnu rẹ̀ isọ.
Ìpìlẹ̀ Meji
(Mat 7:24-27)
46 Ẽsitiṣe ti ẹnyin npè mi li Oluwa, Oluwa, ti ẹnyin kò si ṣe ohun ti mo wi?
47 Ẹnikẹni ti o tọ̀ mi wá, ti o si ngbọ́ ọ̀rọ mi, ti o si nṣe e, emi o fi ẹniti o jọ hàn nyin:
48 O jọ ọkunrin kan ti o kọ́ ile, ti o si walẹ jìn, ti o si fi ipilẹ sọlẹ lori apata: nigbati kíkun omi de, igbi-omi bilù ile na, kò si le mì i: nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori apata.
49 Ṣugbọn ẹniti o gbọ́, ti kò si ṣe, o dabi ọkunrin ti o kọ́ ile si ori ilẹ laini ipilẹ; nigbati igbi-omi bilù u, lọgan o si wó; iwó ile na si pọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Luk 6: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

Àwọn fídíò fún Luk 6