1
Luk 6:38
Bibeli Mimọ
Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Luk 6:38
2
Luk 6:45
Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá; ati enia buburu lati inu iṣura buburu ọkàn rẹ̀ ni imu ohun buburu jade wá: nitori lati ọ̀pọlọpọ ohun ọkàn li ẹnu rẹ̀ isọ.
Ṣàwárí Luk 6:45
3
Luk 6:35
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.
Ṣàwárí Luk 6:35
4
Luk 6:36
Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.
Ṣàwárí Luk 6:36
5
Luk 6:37
Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin
Ṣàwárí Luk 6:37
6
Luk 6:27-28
Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin. Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin.
Ṣàwárí Luk 6:27-28
7
Luk 6:31
Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu.
Ṣàwárí Luk 6:31
8
Luk 6:29-30
Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu. Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère.
Ṣàwárí Luk 6:29-30
9
Luk 6:43
Nitori igi rere kì iso eso buburu; bẹ̃ni igi buburu kì iso eso rere.
Ṣàwárí Luk 6:43
10
Luk 6:44
Olukuluku igi li a ifi eso rẹ̀ mọ̀; nitori lori ẹgún oṣuṣu, enia kì iká eso ọpọtọ bẹ̃ni lori ẹgún ọgàn a kì iká eso ajara.
Ṣàwárí Luk 6:44
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò