Luk 5:20-24

Luk 5:20-24 YBCV

Nigbati o si ri igbagbọ́ wọn, o wi fun u pe, Ọkunrin yi, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. Awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si igberò, wipe, Tali eleyi ti nsọ ọrọ-odi? Tali o le dari ẹ̀ṣẹ jìni bikoṣe Ọlọrun nikanṣoṣo? Ṣugbọn nigbati Jesu mọ̀ ìro inu wọn, o dahùn o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nrò ninu ọkàn nyin? Ewo li o ya jù, lati wipe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide ki iwọ ki o si mã rìn? Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) Mo wi fun ọ, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si lọ si ile rẹ.

Àwọn fídíò fún Luk 5:20-24