Luk 22:1-13

Luk 22:1-13 YBCV

AJỌ ọdun aiwukara ti a npè ni Irekọja si kù fẹfẹ. Ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti ṣe pa a; nitoriti nwọn mbẹ̀ru awọn enia. Satani si wọ̀ inu Judasi, ti a npè ni Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila. O si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o lọ lati ba awọn olori alufa ati awọn olori ẹṣọ́ mọ̀ ọ pọ̀, bi on iba ti fi i le wọn lọwọ. Nwọn si yọ̀, nwọn si ba a da majẹmu ati fun u li owo. O si gbà: o si nwá akoko ti o wọ̀, lati fi i le wọn lọwọ laìsi ariwo. Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja. O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile? O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀. Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ. Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ