Luk 21:1-19

Luk 21:1-19 YBCV

NIGBATI o si gbé oju soke, o ri awọn ọlọrọ̀ nfi ẹ̀bun wọn sinu apoti iṣura. O si ri talakà opó kan pẹlu, o nsọ owo-idẹ wẹ́wẹ meji sibẹ. O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, talakà opó yi fi si i jù gbogbo wọn lọ: Nitori gbogbo awọn wọnyi fi sinu ẹ̀bun Ọlọrun lati ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aìni rẹ̀ o sọ gbogbo ohun ini rẹ̀ ti o ni sinu rẹ̀. Bi awọn kan si ti nsọ̀rọ ti tẹmpili, bi a ti fi okuta daradara ati ẹ̀bun ṣe e li ọṣọ, o ní, Ohun ti ẹnyin nwò wọnyi, ọjọ mbọ̀ li eyi ti a kì yio fi okuta kan silẹ lori ekeji ti a kì yio wó lulẹ. Nwọn si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? ati àmi kini yio wà, nigbati nkan wọnyi yio fi ṣẹ? O si wipe, Ẹ mã kiyesara, ki a má bà mu nyin ṣina: nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, ti yio mã wipe, Emi ni Kristi; akokò igbana si kù si dẹ̀dẹ: ẹ máṣe tọ̀ wọn lẹhin. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gburó ogun ati idagìri, ẹ máṣe foiya: nitori nkan wọnyi ko le ṣe áìkọ́ṣẹ: ṣugbọn opin na kì iṣe lojukanna. Nigbana li o wi fun wọn pe, Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: Isẹlẹ nla yio si wà kakiri, ati ìyan ati ajakalẹ arùn; ohun ẹ̀ru, ati àmi nla yio si ti ọrun wá. Ṣugbọn ṣaju gbogbo nkan wọnyi, nwọn o nawọ́ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagogu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi. Yio si pada di ẹrí fun nyin. Nitorina ẹ pinnu rẹ̀ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun. Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju. A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin. A o si korira nyin lọdọ gbogbo enia nitori orukọ mi. Ṣugbọn irun ori nyin kan kì o ṣegbé. Ninu sũru nyin li ẹnyin o jère ọkàn nyin.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ