Awọn õbi rẹ̀ a si mã lọ si Jerusalemu li ọdọdún si ajọ irekọja. Nigbati o si di ọmọ ọdún mejila, nwọn goke lọ si Jerusalemu gẹgẹ bi iṣe ajọ na. Nigbati ọjọ wọn si pé bi nwọn ti npada bọ̀, ọmọ na Jesu duro lẹhin ni Jerusalemu; Josefu ati iya rẹ̀ kò mọ̀. Ṣugbọn nwọn ṣebi o wà li ẹgbẹ èro, nwọn rìn ìrin ọjọ kan; nwọn wá a kiri ninu awọn ará ati awọn ojulumọ̀ wọn. Nigbati nwọn kò si ri i, nwọn pada si Jerusalemu, nwọn nwá a kiri. O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta nwọn ri i ninu tẹmpili o joko li arin awọn olukọni, o ngbọ́ ti wọn, o si mbi wọn lẽre. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ fun oyé ati idahùn rẹ̀. Nigbati nwọn si ri i, hà ṣe wọn: iya rẹ̀ si bi i pe, Ọmọ, ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃? sawò o, baba rẹ ati emi ti nfi ibinujẹ wá ọ kiri. O si dahùn wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá mi kiri? ẹnyin kò mọ pe, emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi? Ọrọ ti o sọ kò si yé wọn.
Kà Luk 2
Feti si Luk 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 2:41-50
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò