Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e.
A si ti fihàn a lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ na wá pe, on kì yio ri ikú, ki o to ri Kristi Oluwa.
O si ti ipa Ẹmí wá sinu tẹmpili: nigbati awọn obi rẹ̀ si gbé ọmọ na Jesu wá, lati ṣe fun u bi iṣe ofin.
Nigbana li o gbé e li apa rẹ̀, o fi ibukun fun Ọlọrun, o ni,
Oluwa, nigbayi li o to jọwọ ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ lọ li alafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ:
Nitoriti oju mi ti ri igbala rẹ na,
Ti iwọ ti pèse silẹ niwaju enia gbogbo;
Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ.
Ẹnu si yà Josefu ati iya rẹ̀ si nkan ti a nsọ si i wọnyi.
Simeoni si sure fun wọn, o si wi fun Maria iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, a gbé ọmọ yi kalẹ fun iṣubu ati idide ọ̀pọ enia ni Israeli; ati fun àmi ti a nsọ̀rọ òdi si;
(Idà yio si gún iwọ na li ọkàn pẹlu,) ki a le fi ironu ọ̀pọ ọkàn hàn.
Ẹnikan si mbẹ, Anna woli, ọmọbinrin Fanueli, li ẹ̀ya Aseri: ọjọ ogbó rẹ̀ pọ̀, o ti ba ọkọ gbé li ọdún meje lati igba wundia rẹ̀ wá;
O si ṣe opó ìwọn ọdún mẹrinlelọgọrin, ẹniti kò kuro ni tẹmpili, o si nfi àwẹ ati adura sìn Ọlọrun lọsán ati loru.
O si wọle li akokò na, o si dupẹ fun Oluwa pẹlu, o si sọ̀rọ rẹ̀ fun gbogbo awọn ti o nreti idande Jerusalemu.
Nigbati nwọn si ti ṣe nkan gbogbo tan gẹgẹ bi ofin Oluwa, nwọn pada lọ si Galili, si Nasareti ilu wọn.
Ọmọ na si ndàgba, o si nlagbara, o si kún fun ọgbọn: ore-ọfẹ Ọlọrun si mbẹ lara rẹ̀.
Awọn õbi rẹ̀ a si mã lọ si Jerusalemu li ọdọdún si ajọ irekọja.
Nigbati o si di ọmọ ọdún mejila, nwọn goke lọ si Jerusalemu gẹgẹ bi iṣe ajọ na.
Nigbati ọjọ wọn si pé bi nwọn ti npada bọ̀, ọmọ na Jesu duro lẹhin ni Jerusalemu; Josefu ati iya rẹ̀ kò mọ̀.
Ṣugbọn nwọn ṣebi o wà li ẹgbẹ èro, nwọn rìn ìrin ọjọ kan; nwọn wá a kiri ninu awọn ará ati awọn ojulumọ̀ wọn.
Nigbati nwọn kò si ri i, nwọn pada si Jerusalemu, nwọn nwá a kiri.
O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta nwọn ri i ninu tẹmpili o joko li arin awọn olukọni, o ngbọ́ ti wọn, o si mbi wọn lẽre.
Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ fun oyé ati idahùn rẹ̀.
Nigbati nwọn si ri i, hà ṣe wọn: iya rẹ̀ si bi i pe, Ọmọ, ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃? sawò o, baba rẹ ati emi ti nfi ibinujẹ wá ọ kiri.
O si dahùn wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá mi kiri? ẹnyin kò mọ pe, emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi?
Ọrọ ti o sọ kò si yé wọn.
O si ba wọn sọkalẹ lọ si Nasareti, o si fi ara balẹ fun wọn: ṣugbọn iya rẹ̀ pa gbogbo nkan wọnyi mọ́ ninu ọkàn rẹ̀.
Jesu si npọ̀ li ọgbọ́n, o si ndàgba, o si wà li ojurere li ọdọ Ọlọrun ati enia.