Luk 2:21-38

Luk 2:21-38 YBCV

Nigbati ijọ mẹjọ si pé lati kọ ọmọ na nila, nwọn pè orukọ rẹ̀ ni JESU, bi a ti sọ ọ tẹlẹ lati ọdọ angẹli na wá ki a to lóyun rẹ̀ ninu. Nigbati ọjọ iwẹnu Maria si pé gẹgẹ bi ofin Mose, nwọn gbé Jesu wá si Jerusalemu lati fi i fun Oluwa; (Bi a ti kọ ọ sinu ofin Oluwa pe, Gbogbo ọmọ ọkunrin ti o ṣe akọbi, on li a o pè ni mimọ́ fun Oluwa;) Ati lati rubọ gẹgẹ bi eyi ti a wi ninu ofin Oluwa, Àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e. A si ti fihàn a lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ na wá pe, on kì yio ri ikú, ki o to ri Kristi Oluwa. O si ti ipa Ẹmí wá sinu tẹmpili: nigbati awọn obi rẹ̀ si gbé ọmọ na Jesu wá, lati ṣe fun u bi iṣe ofin. Nigbana li o gbé e li apa rẹ̀, o fi ibukun fun Ọlọrun, o ni, Oluwa, nigbayi li o to jọwọ ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ lọ li alafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: Nitoriti oju mi ti ri igbala rẹ na, Ti iwọ ti pèse silẹ niwaju enia gbogbo; Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ. Ẹnu si yà Josefu ati iya rẹ̀ si nkan ti a nsọ si i wọnyi. Simeoni si sure fun wọn, o si wi fun Maria iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, a gbé ọmọ yi kalẹ fun iṣubu ati idide ọ̀pọ enia ni Israeli; ati fun àmi ti a nsọ̀rọ òdi si; (Idà yio si gún iwọ na li ọkàn pẹlu,) ki a le fi ironu ọ̀pọ ọkàn hàn. Ẹnikan si mbẹ, Anna woli, ọmọbinrin Fanueli, li ẹ̀ya Aseri: ọjọ ogbó rẹ̀ pọ̀, o ti ba ọkọ gbé li ọdún meje lati igba wundia rẹ̀ wá; O si ṣe opó ìwọn ọdún mẹrinlelọgọrin, ẹniti kò kuro ni tẹmpili, o si nfi àwẹ ati adura sìn Ọlọrun lọsán ati loru. O si wọle li akokò na, o si dupẹ fun Oluwa pẹlu, o si sọ̀rọ rẹ̀ fun gbogbo awọn ti o nreti idande Jerusalemu.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Luk 2:21-38