Luk 16

16
Òwe Ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n Ẹ̀wẹ́
1O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu pe, Ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o ni iriju kan; on na ni nwọn fi sùn u pe, o ti nfi ohun-ini rẹ̀ ṣòfo.
2 Nigbati o si pè e, o wi fun u pe, Ẽṣe ti emi fi ngbọ́ eyi si ọ? siro iṣẹ iriju rẹ; nitori iwọ ko le ṣe iriju mọ́.
3 Iriju na si wi ninu ara rẹ̀ pe, Ewo li emi o ṣe? nitoriti Oluwa mi gbà iṣẹ iriju lọwọ mi: emi kò le wàlẹ; lati ṣagbe oju ntì mi.
4 Mo mọ̀ eyiti emi o ṣe, nigbati a ba mu mi kuro nibi iṣẹ iriju, ki nwọn ki o le gbà mi sinu ile wọn.
5 O si pè awọn ajigbese oluwa rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun ekini pe, Elo ni iwọ jẹ oluwa mi?
6 O si wipe, Ọgọrun oṣuwọn oróro. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, si joko nisisiyi, ki o si kọ adọta.
7 Nigbana li o si bi ẹnikeji pe, Elo ni iwọ jẹ? On si wipe, Ọgọrun oṣuwọn alikama. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, ki o si kọ ọgọrin.
8 Oluwa rẹ̀ si yìn alaiṣõtọ iriju na, nitoriti o fi ọgbọ́n ṣe e: awọn ọmọ aiye yi sá gbọ́n ni iran wọn jù awọn ọmọ imọlẹ lọ.
9 Emi si wi fun nyin, ẹ fi mammoni aiṣõtọ yàn ọrẹ́ fun ara nyin pe, nigbati yio ba yẹ̀, ki nwọn ki o le gbà nyin si ibujoko wọn titi aiye.
10 Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipo pẹlu.
11 Njẹ bi ẹnyin kò ba ti jẹ olõtọ ni mammoni aiṣõtọ, tani yio fi ọrọ̀ tõtọ ṣú nyin?
12 Bi ẹnyin ko ba si ti jẹ olõtọ li ohun ti iṣe ti ẹlomiran, tani yio fun nyin li ohun ti iṣe ti ẹnyin tikara nyin?
13 Kò si iranṣẹ kan ti o le sin oluwa meji: ayaṣebi yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio fi ara mọ́ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin kò le sin Ọlọrun pẹlu mammoni.
Òfin ati Ìjọba Ọlọrun
(Mat 11:12-13; 5:31-32; Mak 10:11-12)
14Awọn Farisi, ti nwọn ni ojukokoro si gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, nwọn si yọ-ṣùti si i.
15O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun.
16 Ofin ati awọn woli mbẹ titi di igba Johanu: lati igbana wá li a ti nwasu ijọba Ọlọrun, olukuluku si nfi ipá wọ̀ inu rẹ̀.
17 Ṣugbọn o rọrun fun ọrun on aiye lati kọja lọ, jù ki ṣonṣo kan ti ofin ki o yẹ̀.
18 Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé, ẹniti ọkọ rẹ̀ kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.
Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ ati Lasaru
19 Njẹ ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o nwọ̀ aṣọ elesè àluko ati aṣọ àla daradara, a si ma jẹ didùndidun lojojumọ́:
20 Alagbe kan si wà ti a npè ni Lasaru, ti nwọn ima gbé wá kalẹ lẹba ọ̀na ile rẹ̀, o kún fun õju,
21 On a si ma fẹ ki a fi ẹrún ti o ti ori tabili ọlọrọ̀ bọ silẹ bọ́ on: awọn ajá si wá, nwọn si fá a li õju lá.
22 O si ṣe, alagbe kú, a si ti ọwọ́ awọn angẹli gbé e lọ si õkan-àiya Abrahamu: ọlọrọ̀ na si kú pẹlu, a si sin i;
23 Ni ipo-oku li o gbé oju rẹ̀ soke, o mbẹ ninu iṣẹ oró, o si ri Abrahamu li òkere, ati Lasaru li õkan-àiya rẹ̀.
24 O si ke, o wipe, Baba Abrahamu, ṣãnu fun mi, ki o si rán Lasaru, ki o tẹ̀ orika rẹ̀ bọmi, ki o si fi tù mi li ahọn; nitori emi njoró ninu ọwọ́ iná yi.
25 Ṣugbọn Abrahamu wipe, Ọmọ, ranti pe, nigba aiye rẹ, iwọ ti gbà ohun rere tirẹ, ati Lasaru ohun buburu: ṣugbọn nisisiyi ara rọ̀ ọ, iwọ si njoro.
26 Ati pẹlu gbogbo eyi, a gbe ọgbun nla kan si agbedemeji awa ati ẹnyin, ki awọn ti nfẹ má ba le rekọja lati ìhin lọ sọdọ nyin, ki ẹnikẹni má si le ti ọ̀hun rekọja tọ̀ wa wá.
27 O si wipe, Njẹ mo bẹ̀ ọ, baba, ki iwọ ki o rán a lọ si ile baba mi:
28 Nitori mo ni arakunrin marun; ki o le rò fun wọn ki awọn ki o má ba wá si ibi oró yi pẹlu.
29 Abrahamu si wi fun u pe, Nwọn ni Mose ati awọn woli; ki nwọn ki o gbọ́ ti wọn.
30 O si wipe, Bẹ̃kọ, Abrahamu baba; ṣugbọn bi ẹnikan ba ti inu okú tọ̀ wọn lọ, nwọn ó ronupiwada.
31 O si wi fun u pe, Bi nwọn kò ba gbọ́ ti Mose ati ti awọn woli, a kì yio yi wọn li ọkan pada bi ẹnikan tilẹ ti inu okú dide.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Luk 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

Àwọn fídíò fún Luk 16