O si wipe, Ọkunrin kan li ọmọkunrin meji:
Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn.
Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna.
Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini.
O si lọ, o da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ kan ni ilẹ na; on si rán a lọ si oko rẹ̀ lati tọju ẹlẹdẹ.
Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u.
Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin.
Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ;
Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ.
O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.
Ọmọ na si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ, emi kò yẹ li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́.
Ṣugbọn baba na wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mu ãyo aṣọ wá kánkán, ki ẹ si fi wọ̀ ọ; ẹ si fi oruka bọ̀ ọ lọwọ, ati bàta si ẹsẹ rẹ̀:
Ẹ si mu ẹgbọ̀rọ malu abọpa wá, ki ẹ si pa a; ki a mã jẹ, ki a si mã ṣe ariya:
Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i. Nwọn si bẹ̀re si iṣe ariya.