Nigbana li o si wi fun alase ti o pè e pe, Nigbati iwọ ba se àse ọsán, tabi àse alẹ, má pè awọn ọrẹ́ rẹ, tabi awọn arakunrin rẹ, tabi awọn ibatan rẹ, tabi awọn aladugbo rẹ ọlọrọ̀; nitori ki nwọn ki o má ṣe pè ọ ẹ̀wẹ lati san ẹsan fun ọ.
Ṣugbọn nigbati iwọ ba se àse, pè awọn talakà, awọn alabùkù arùn, awọn amukun, ati awọn afọju:
Iwọ o si jẹ alabukun fun; nitori nwọn kò ni ohun ti nwọn o fi san a fun ọ: ṣugbọn a o san a fun ọ li ajinde awọn olõtọ.
Nigbati ọkan ninu awọn ti o ba a joko tì onjẹ gbọ́ nkan wọnyi, o wi fun u pe, Ibukun ni fun ẹniti yio jẹun ni ijọba Ọlọrun.
Ṣugbọn o wi fun u pe, Ọkunrin kan se àse-alẹ nla, o si pè enia pipọ:
O si rán ọmọ-odọ rẹ̀ ni wakati àse-alẹ lati sọ fun awọn ti a ti pè wipe, Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan.
Gbogbo wọn so bẹ̀rẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi. Ekini wi fun u pe, Mo rà ilẹ kan, emi kò si le ṣe ki ng má lọ iwò o: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi.
Ekeji si wipe, Mo rà ajaga malu marun, mo si nlọ idán wọn wò: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi.
Ẹkẹta si wipe, Mo gbeyawo, nitorina li emi kò fi le wá.
Ọmọ-ọdọ na si pada de, o sọ nkan wọnyi fun oluwa rẹ̀. Nigbana ni bãle ile binu, o wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Jade lọ si igboro, ati si abuja ọ̀na, ki o si mu awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amukun, ati awọn afọju wá si ihinyi.
Ọmọ-ọdọ na si wipe, Oluwa, a ti ṣe bi o ti paṣẹ, àye si mbẹ sibẹ.
Oluwa na si wi fun ọmọ-ọdọ na pe, Jade lọ si opópo, ati si ọ̀na ọgbà, ki o si rọ̀ wọn lati wọle wá, ki ile mi le kún.
Nitori mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ninu awọn enia wọnyi ti a ti pè, ki yio tọwò ninu àse-alẹ mi.