Mo si wi fun nyin pẹlu, Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, Ọmọ-ẹnia yio si jẹwọ rẹ̀ niwaju awọn angẹli Ọlọrun:
Ṣugbọn ẹniti o ba sẹ́ mi niwaju enia, a o sẹ́ ẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun.
Ati ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ-òdi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a kì yio dari rẹ̀ jì i.
Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagogu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi:
Nitori Ẹmí Mimọ́ yio kọ́ nyin ni wakati kanna li ohun ti o yẹ ki ẹ wi.
Ọkan ninu awujọ si wi fun u pe, Olukọni, sọ fun arakunrin mi ki o pín mi li ogún.
O si wi fun u pe, Ọkunrin yi, tali o fi mi jẹ onidajọ tabi olùpín-ogún wá fun nyin?
O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni.
O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ:
O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si?
O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si.
Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀.
Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?
Bẹ̃ li ẹniti o tò iṣura jọ fun ara rẹ̀, ti ko si li ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.
O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora.
Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ.
Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ?
Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀?
Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù?
Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi.
Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere?
Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji.
Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi.
Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin.
Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin.
Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ.
Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.