Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin.
Kà Luk 12
Feti si Luk 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 12:27-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò