Luk 12:22-34

Luk 12:22-34 YBCV

O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora. Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ. Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ? Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù? Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin. Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin. Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ. Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa