Luk 12:22-34

Luk 12:22-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora. Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ. Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ? Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù? Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin. Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin. Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ. Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.

Luk 12:22-34 Yoruba Bible (YCE)

Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa páyà nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Nítorí ẹ̀mí ṣe pataki ju oúnjẹ lọ, ara sì ṣe pataki ju aṣọ lọ. Ẹ ṣe akiyesi àwọn ẹyẹ; wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè. Wọn kò ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà. Sibẹ Ọlọrun ń bọ́ wọn. Mélòó-mélòó ni ẹ fi sàn ju àwọn ẹyẹ lọ. Ta ni ninu yín tí ó lè páyà títí dé ibi pé yóo fi ẹsẹ̀ bàtà kan kún gíga rẹ̀? Nítorí náà, bí ẹ kò bá lè ṣe ohun tí ó kéré jùlọ, kí ló dé tí ẹ fi ń páyà nípa àwọn nǹkan yòókù? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu ọlá rẹ̀ kò wọ aṣọ tí ó dára tó wọn. Bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo fi aṣọ wọ̀ yín, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré yìí! “Nítorí náà, ẹ̀yin ẹ má máa páyà kiri nítorí ohun tí ẹ óo jẹ. (Nítorí pé irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn alaigbagbọ ayé yìí ń dààmú kiri sí.) Baba yín sá mọ̀ pé ẹ nílò wọn. Ṣugbọn kí ẹ máa kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni yóo fun yín pẹlu. “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fun yín ní ìjọba rẹ̀. Ẹ ta àwọn ohun tí ẹ ní, kí ẹ fi ṣe ìtọrẹ-àánú. Ẹ dá àpò fún ara yín tí kò ní gbó laelae; ẹ to ìṣúra tí ó dájú jọ sí ọ̀run, níbi tí olè kò lè súnmọ́, tí kòkòrò kò sì lè ba nǹkan jẹ́. Nítorí níbi tí ìṣúra yín bá wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín náà yóo wà.

Luk 12:22-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù? “Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín. “Má bẹ̀rù, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín. Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́. Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.