O si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ mã wipe, Baba wa ti mbẹ li ọrun, Ki a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹni li aiye.
Fun wa li onjẹ ojọ wa li ojojumọ́.
Ki o si dari ẹ̀ṣẹ wa jì wa; nitori awa tikarawa pẹlu a ma darijì olukuluku ẹniti o jẹ wa ni gbese. Má si fà wa sinu idẹwò; ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi.
O si wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti yio ni ọrẹ́ kan, ti yio si tọ̀ ọ lọ larin ọganjọ, ti yio si wi fun u pe, Ọrẹ́, win mi ni ìṣu akara mẹta:
Nitori ọrẹ́ mi kan ti àjo bọ sọdọ mi, emi kò si ni nkan ti emi o gbé kalẹ niwaju rẹ̀;
Ti on o si gbé inu ile dahùn wi fun u pe, Má yọ mi lẹnu: a ti sé ilẹkun na, awọn ọmọ mi si mbẹ lori ẹní pẹlu mi; emi ko le dide fifun ọ?
Mo wi fun nyin, bi on kò tilẹ fẹ dide ki o fifun u, nitoriti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nitori awiyannu rẹ̀ yio dide, yio si fun u pọ̀ to bi o ti nfẹ.
Emi si wi fun nyin, Ẹ bère, a o si fifun nyin; ẹ wá kiri, ẹnyin o si ri; ẹ kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin.
Nitori ẹnikẹni ti o ba bère, o ri gbà; ẹniti o si nwá kiri o ri; ati ẹniti o kànkun li a o ṣí i silẹ fun.
Tani iṣe baba ninu nyin ti ọmọ rẹ̀ yio bère akara lọdọ rẹ̀, ti o jẹ fun u li okuta? tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò dipo ẹja?
Tabi bi o si bère ẹyin, ti o jẹ fun u li akẽkẽ?
Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu ba mọ̀ bi ãti ifi ẹ̀bun didara fun awọn ọmọ nyin: melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ fun awọn ti o mbère lọdọ rẹ̀?