Luk 11:14-54

Luk 11:14-54 YBCV

O si nlé ẹmi èṣu kan jade, ti o si yadi. O si ṣe, nigbati ẹmi èṣu na jade, odi sọrọ; ẹnu si yà ijọ enia. Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn wipe, Nipa Beelsebubu olori awọn ẹmi èṣu li o fi nlé awọn ẹmi èṣu jade. Awọn ẹlomiran si ndan a wò, nwọn fẹ àmi lọdọ rẹ̀ lati ọrun wá. Ṣugbọn on mọ̀ ìro inu wọn, o wi fun wọn pe, Gbogbo ijọba ti o yà ara rẹ̀ ni ipa, a sọ ọ di ahoro; ile ti o si yà ara rẹ̀ ni ipa, a wó. Bi Satani si yàpa si ara rẹ̀, ijọba rẹ̀ yio ha ṣe duro? nitori ẹnyin wipe, Nipa Beelsebubu li emi fi nle awọn ẹmi èṣu jade. Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina awọn ni yio ṣe onidajọ nyin. Ṣugbọn bi o ba ṣepe ika Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, kò si aniani, ijọba Ọlọrun de ba nyin. Nigbati ọkunrin alagbara ti o hamọra ba nṣọ afin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wà li alãfia: Ṣugbọn nigbati ẹniti o li agbara jù u ba kọlù u, ti o si ṣẹgun rẹ̀, a gbà gbogbo ihamọra rẹ̀ ti o gbẹkẹle lọwọ rẹ̀, a si pín ikogun rẹ̀. Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o lodi si mi: ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfunká. Nigbati ẹmi aimọ́ ba jade kuro lara enia, ama rìn kiri ni ibi gbigbẹ, ama wá ibi isimi; nigbati ko ba si ri, a wipe, Emi o pada lọ si ile mi nibiti mo gbé ti jade wá. Nigbati o si de, o bá a, a gbá a, a si ṣe e li ọṣọ́. Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibẹ̀: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. O si ṣe, bi o ti nsọ nkan wọnyi, obinrin kan nahùn ninu ijọ, o si wi fun u pe, Ibukun ni fun inu ti o bí ọ, ati ọmú ti iwọ mu. Ṣugbọn on wipe, Nitõtọ, ki a kuku wipe, Ibukun ni fun awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si pa a mọ́. Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ sí wipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli. Nitori bi Jona ti jẹ àmi fun awọn ara Ninefe, gẹgẹ bẹ̃ li Ọmọ-enia yio ṣe àmi fun iran yi. Ọbabirin gusù yio dide li ọjọ idajọ pẹlu awọn enia iran yi, yio si da wọn lẹbi: nitoriti o ti iha ipẹkun aiye wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi. Awọn ara Ninefe yio dide li ọjọ idajọ pẹlu iran yi, nwọn o si da a lẹbi: nitoriti nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Jona lọ mbẹ nihinyi. Kò si ẹnikan, nigbati o ba tan fitila tán, ti igbé e si ìkọkọ, tabi sabẹ oṣuwọn, bikoṣe sori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọle ba le mã ri imọlẹ. Oju ni imọlẹ ara: bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ a mọlẹ; ṣugbọn bi oju rẹ ba buru, ara rẹ pẹlu a kun fun òkunkun. Nitorina kiyesi i, ki imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ki o máṣe di òkunkun. Njẹ bi gbogbo ara rẹ ba kun fun imọlẹ, ti ko li apakan ti o ṣokunkun, ara rẹ, gbogbo ni yio kun fun imọlẹ, bi igbati fitila ba fi itanṣan rẹ̀ fun ọ ni imọlẹ. Bi o si ti nwi, Farisi kan bẹ̀ ẹ ki o ba on jẹun: o si wọle, o joko lati jẹun. Nigbati Farisi na si ri i, ẹnu yà a nitoriti kò kọ́ wẹ̀ ki o to jẹun. Oluwa si wi fun u pe, Ẹnyin Farisi a ma fọ̀ ode ago ati awopọkọ́; ṣugbọn inu nyin kún fun irẹjẹ iwa-buburu. Ẹnyin alaimoye, ẹniti o ṣe eyi ti mbẹ lode, on kọ́ ha ṣe eyi ti mbẹ ninu pẹlu? Ki ẹnyin ki o kuku mã ṣe itọrẹ ãnu ninu ohun ti ẹnyin ni; si kiyesi i, ohun gbogbo li o di mimọ́ fun nyin. Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin a ma san idamẹwa minti, ati rue, ati gbogbo ewebẹ̀, ṣugbọn ẹnyin gbojufò idajọ ati ifẹ Ọlọrun: wọnyi li ẹnyin iba ṣe, ẹ kì ba si ti fi ekeji silẹ laiṣe. Egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin fẹ ipò-ọlá ninu sinagogu, ati ikí-ni li ọjà. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe, ati ẹnyin Farisi, agabagebe! nitoriti ẹnyin dabi isa okú ti kò hàn, awọn enia ti o si nrìn lori wọn kò mọ̀. Nigbana li ọkan ninu awọn amofin dahùn, o si wi fun u pe, Olukọni, li eyi ti iwọ nwi nì iwọ ngàn awa pẹlu. O si wipe, Egbé ni fun ẹnyin amofin pẹlu! nitoriti ẹnyin di ẹrù ti o wuwo lati rù le enia lori, bẹ̃ni ẹnyin tikara nyin kò jẹ fi ika nyin kan kàn ẹrù na. Egbé ni fun nyin! nitoriti ẹnyin kọ́le oju-õrì awọn woli, awọn baba nyin li o si ti pa wọn. Njẹ ẹnyin njẹ ẹlẹri, ẹ si ni inudidun si iṣe awọn baba nyin: nitori nwọn pa wọn, ẹnyin si kọ́le oju-õrì wọn. Nitori eyi li ọgbọ́n Ọlọrun si ṣe wipe, emi ó rán awọn woli ati awọn aposteli si wọn, ninu wọn ni nwọn o si pa, ti nwọn o si ṣe inunibini si: Ki a le bère ẹ̀jẹ awọn woli gbogbo, ti a ti ta silẹ lati igba ipilẹṣẹ aiye wá, lọdọ iran yi; Lati ẹ̀jẹ Abeli wá, titi o si fi de ẹ̀jẹ Sakariah, ti o ṣegbé lãrin pẹpẹ on tẹmpili: lõtọ ni mo wi fun nyin, A o bère rẹ̀ lọdọ iran yi. Egbé ni fun nyin, ẹnyin amofin! nitoriti ẹnyin gbà ọmọ-ṣika ìmọ: ẹnyin tikaranyin kò wọle, awọn ti si nwọle, li ẹnyin kọ̀ fun. Bi o ti nwi nkan wọnyi fun wọn, awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si ibinu si i gidigidi, nwọn si nyọ ọ́ lẹnu lati wi nkan pipọ: Nwọn nṣọ ọ, nwọn nwá ọ̀na ati ri nkan gbámu li ẹnu rẹ̀, ki nwọn ki o le fi i sùn.

Àwọn fídíò fún Luk 11:14-54