O si nlé ẹmi èṣu kan jade, ti o si yadi. O si ṣe, nigbati ẹmi èṣu na jade, odi sọrọ; ẹnu si yà ijọ enia.
Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn wipe, Nipa Beelsebubu olori awọn ẹmi èṣu li o fi nlé awọn ẹmi èṣu jade.
Awọn ẹlomiran si ndan a wò, nwọn fẹ àmi lọdọ rẹ̀ lati ọrun wá.
Ṣugbọn on mọ̀ ìro inu wọn, o wi fun wọn pe, Gbogbo ijọba ti o yà ara rẹ̀ ni ipa, a sọ ọ di ahoro; ile ti o si yà ara rẹ̀ ni ipa, a wó.
Bi Satani si yàpa si ara rẹ̀, ijọba rẹ̀ yio ha ṣe duro? nitori ẹnyin wipe, Nipa Beelsebubu li emi fi nle awọn ẹmi èṣu jade.
Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina awọn ni yio ṣe onidajọ nyin.
Ṣugbọn bi o ba ṣepe ika Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, kò si aniani, ijọba Ọlọrun de ba nyin.
Nigbati ọkunrin alagbara ti o hamọra ba nṣọ afin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wà li alãfia:
Ṣugbọn nigbati ẹniti o li agbara jù u ba kọlù u, ti o si ṣẹgun rẹ̀, a gbà gbogbo ihamọra rẹ̀ ti o gbẹkẹle lọwọ rẹ̀, a si pín ikogun rẹ̀.
Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o lodi si mi: ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfunká.
Nigbati ẹmi aimọ́ ba jade kuro lara enia, ama rìn kiri ni ibi gbigbẹ, ama wá ibi isimi; nigbati ko ba si ri, a wipe, Emi o pada lọ si ile mi nibiti mo gbé ti jade wá.
Nigbati o si de, o bá a, a gbá a, a si ṣe e li ọṣọ́.
Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibẹ̀: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ.
O si ṣe, bi o ti nsọ nkan wọnyi, obinrin kan nahùn ninu ijọ, o si wi fun u pe, Ibukun ni fun inu ti o bí ọ, ati ọmú ti iwọ mu.
Ṣugbọn on wipe, Nitõtọ, ki a kuku wipe, Ibukun ni fun awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si pa a mọ́.
Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ sí wipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli.
Nitori bi Jona ti jẹ àmi fun awọn ara Ninefe, gẹgẹ bẹ̃ li Ọmọ-enia yio ṣe àmi fun iran yi.
Ọbabirin gusù yio dide li ọjọ idajọ pẹlu awọn enia iran yi, yio si da wọn lẹbi: nitoriti o ti iha ipẹkun aiye wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi.
Awọn ara Ninefe yio dide li ọjọ idajọ pẹlu iran yi, nwọn o si da a lẹbi: nitoriti nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Jona lọ mbẹ nihinyi.
Kò si ẹnikan, nigbati o ba tan fitila tán, ti igbé e si ìkọkọ, tabi sabẹ oṣuwọn, bikoṣe sori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọle ba le mã ri imọlẹ.
Oju ni imọlẹ ara: bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ a mọlẹ; ṣugbọn bi oju rẹ ba buru, ara rẹ pẹlu a kun fun òkunkun.
Nitorina kiyesi i, ki imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ki o máṣe di òkunkun.
Njẹ bi gbogbo ara rẹ ba kun fun imọlẹ, ti ko li apakan ti o ṣokunkun, ara rẹ, gbogbo ni yio kun fun imọlẹ, bi igbati fitila ba fi itanṣan rẹ̀ fun ọ ni imọlẹ.