Luk 11:1-28

Luk 11:1-28 YBCV

O si ṣe, bi o ti ngbadura ni ibi kan, bi o ti dakẹ, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, kọ́ wa bi ãti igbadura, bi Johanu si ti kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ mã wipe, Baba wa ti mbẹ li ọrun, Ki a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹni li aiye. Fun wa li onjẹ ojọ wa li ojojumọ́. Ki o si dari ẹ̀ṣẹ wa jì wa; nitori awa tikarawa pẹlu a ma darijì olukuluku ẹniti o jẹ wa ni gbese. Má si fà wa sinu idẹwò; ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. O si wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti yio ni ọrẹ́ kan, ti yio si tọ̀ ọ lọ larin ọganjọ, ti yio si wi fun u pe, Ọrẹ́, win mi ni ìṣu akara mẹta: Nitori ọrẹ́ mi kan ti àjo bọ sọdọ mi, emi kò si ni nkan ti emi o gbé kalẹ niwaju rẹ̀; Ti on o si gbé inu ile dahùn wi fun u pe, Má yọ mi lẹnu: a ti sé ilẹkun na, awọn ọmọ mi si mbẹ lori ẹní pẹlu mi; emi ko le dide fifun ọ? Mo wi fun nyin, bi on kò tilẹ fẹ dide ki o fifun u, nitoriti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nitori awiyannu rẹ̀ yio dide, yio si fun u pọ̀ to bi o ti nfẹ. Emi si wi fun nyin, Ẹ bère, a o si fifun nyin; ẹ wá kiri, ẹnyin o si ri; ẹ kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin. Nitori ẹnikẹni ti o ba bère, o ri gbà; ẹniti o si nwá kiri o ri; ati ẹniti o kànkun li a o ṣí i silẹ fun. Tani iṣe baba ninu nyin ti ọmọ rẹ̀ yio bère akara lọdọ rẹ̀, ti o jẹ fun u li okuta? tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò dipo ẹja? Tabi bi o si bère ẹyin, ti o jẹ fun u li akẽkẽ? Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu ba mọ̀ bi ãti ifi ẹ̀bun didara fun awọn ọmọ nyin: melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ fun awọn ti o mbère lọdọ rẹ̀? O si nlé ẹmi èṣu kan jade, ti o si yadi. O si ṣe, nigbati ẹmi èṣu na jade, odi sọrọ; ẹnu si yà ijọ enia. Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn wipe, Nipa Beelsebubu olori awọn ẹmi èṣu li o fi nlé awọn ẹmi èṣu jade. Awọn ẹlomiran si ndan a wò, nwọn fẹ àmi lọdọ rẹ̀ lati ọrun wá. Ṣugbọn on mọ̀ ìro inu wọn, o wi fun wọn pe, Gbogbo ijọba ti o yà ara rẹ̀ ni ipa, a sọ ọ di ahoro; ile ti o si yà ara rẹ̀ ni ipa, a wó. Bi Satani si yàpa si ara rẹ̀, ijọba rẹ̀ yio ha ṣe duro? nitori ẹnyin wipe, Nipa Beelsebubu li emi fi nle awọn ẹmi èṣu jade. Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina awọn ni yio ṣe onidajọ nyin. Ṣugbọn bi o ba ṣepe ika Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, kò si aniani, ijọba Ọlọrun de ba nyin. Nigbati ọkunrin alagbara ti o hamọra ba nṣọ afin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wà li alãfia: Ṣugbọn nigbati ẹniti o li agbara jù u ba kọlù u, ti o si ṣẹgun rẹ̀, a gbà gbogbo ihamọra rẹ̀ ti o gbẹkẹle lọwọ rẹ̀, a si pín ikogun rẹ̀. Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o lodi si mi: ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfunká. Nigbati ẹmi aimọ́ ba jade kuro lara enia, ama rìn kiri ni ibi gbigbẹ, ama wá ibi isimi; nigbati ko ba si ri, a wipe, Emi o pada lọ si ile mi nibiti mo gbé ti jade wá. Nigbati o si de, o bá a, a gbá a, a si ṣe e li ọṣọ́. Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibẹ̀: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. O si ṣe, bi o ti nsọ nkan wọnyi, obinrin kan nahùn ninu ijọ, o si wi fun u pe, Ibukun ni fun inu ti o bí ọ, ati ọmú ti iwọ mu. Ṣugbọn on wipe, Nitõtọ, ki a kuku wipe, Ibukun ni fun awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si pa a mọ́.

Àwọn fídíò fún Luk 11:1-28