Lef Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àwọn ìlànà ìjọ́sìn ati ayẹyẹ tí ó jẹ mọ́ ẹ̀sìn ilẹ̀ Israẹli àtijọ́, ati òfin tí ó de àwọn àlùfáà tí wọn ń darí ìjọ́sìn ati ayẹyẹ náà, ló wà ninu Ìwé Lefitiku.
Kókó pataki inú ìwé yìí ni Mímọ́ Ọlọrun, àwọn ọ̀nà tí àwọn eniyan rẹ̀ ń gbà sìn ín, ati irú ìgbé ayé tí wọn ń gbé kí wọ́n lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu “Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli.”
Gbolohun kan tí àwọn eniyan mọ̀ jùlọ ninu ìwé yìí wà ní orí 19, ẹsẹ 18. Òun ni Jesu pè ní òfin ńlá keji. Gbolohun náà ni: “Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àwọn òfin tí ó de ẹbọ rírú ati ọrẹ 1:1—7:38
Ètò fífi Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ oyè àlùfáà 8:1—10:20
Òfin nípa ètùtù fún jíjẹ́ mímọ́ ati jíjẹ́ aláìmọ́ ní ọ̀nà ti ẹ̀sìn 11:1—15:33
Ọjọ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ 16:1-34
Òfin nípa ìgbé ayé mímọ́ ati ìjọ́sìn tí ó jẹ́ mímọ́ 17:1—27:34

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Lef Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀