Ẹk. Jer Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé yìí jẹ́ àkójọpọ̀ orin arò marun-un nípa ìṣubú Jerusalẹmu ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla kí á tó bí OLUWA wa, (586 B.C.), ati ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ogun kó Jerusalẹmu, tí a sì kó àwọn Juu lọ sí ìgbèkùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohùn arò kún inú ìwé yìí, ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ati ìrètí ninu Ọlọrun ṣì tún wà níbẹ̀. Wọn a máa lo àwọn orin arò wọnyii lọdọọdun ní àkókò ààwẹ̀ ati ìrònú nípa ìrántí ìṣòro tí orílẹ̀-èdè wọn ní, ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla kí á tó bí OLUWA wa, (586 B.C.), tí ogun kó Jerusalẹmu.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àwọn ìṣòro tí ó kojú Jerusalẹmu 1:1-22
Ìjìyà Jerusalẹmu 2:1-22
Ìjìyà ati ìrètí 3:1-66
Jerusalẹmu pa run 4:1-22
Adura àánú 5:1-22

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ẹk. Jer Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀