Ẹk. Jer 3:1-26

Ẹk. Jer 3:1-26 YBCV

EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀. O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ. Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo. O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi. O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka. O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ. O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo. Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ. O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po. On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ. O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro. O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀. O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ. Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ. O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala. O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru. Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere. Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa. Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀. O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa.