Jud 1

1
Ìkíni
1JUDA, iranṣẹ Jesu Kristi, ati arakunrin Jakọbu, si awọn ti a pè, olufẹ ninu Ọlọrun Baba, ti a si pamọ́ fun Jesu Kristi:
2Ki ãnu, ati alafia, ati ifẹ ki o mã bi si i fun nyin.
Ìdájọ́ fún àwọn èké olùkọ́ni
(II. Pet 2:1-17)
3Olufẹ, nigbati mo fi aisimi gbogbo kọwe si nyin niti igbala ti iṣe ti gbogbo enia, nko gbọdọ ṣaima kọwé si nyin, ki n si gbà nyin niyanju lati mã ja gidigidi fun igbagbọ́, ti a ti fi lé awọn enia mimọ́ lọwọ lẹ̃kanṣoṣo.
4Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.
5Njẹ emi nfẹ lati rán nyin leti bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ gbogbo rẹ̀ lẹ̃kan ri, pe Oluwa, nigbati o ti gbà awọn enia kan là lati ilẹ Egipti wá, lẹhinna o run awọn ti kò gbagbọ́.
6Ati awọn angẹli ti kò tọju ipò ọla wọn ṣugbọn ti nwọn fi ipò wọn silẹ, awọn ni o pamọ́ ninu ẹ̀wọn ainipẹkun nisalẹ òkunkun de idajọ ọjọ nla nì.
7Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun.
8Bakanna ni awọn wọnyi pẹlu nsọ ara di ẽri ninu àlá wọn, nwọn si ngan ijoye, nwọn si nsọ̀rọ buburu si awọn ọlọlá.
9Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi.
10Ṣugbọn awọn wọnyi nsọ̀rọ-òdi si ohun gbogbo ti nwọn kò mọ̀: ṣugbọn ohun gbogbo ti nwọn mọ̀ nipa ẹda, bi ẹranko tí kò ni iyè, ninu nkan wọnyi ni nwọn di ẹni iparun.
11Egbé ni fun wọn! Nitoriti nwọn ti rìn li ọ̀na Kaini, nwọn si fi iwọra súré sinu ìṣina Balaamu nitori ère, nwọn si ṣegbé ninu iṣọtẹ̀ Kora.
12Awọn wọnyi li o jẹ abawọn ninu àse ifẹ nyin, nigbati nwọn mba nyin jẹ ase, awọn oluṣọ-agutan ti mbọ́ ara wọn laibẹru: ikũku laini omi, ti a nti ọwọ afẹfẹ gbá kiri: awọn igi alaileso li akoko eso, nwọn kú lẹ̃meji, a fà wọn tu ti gbongbo ti gbongbo;
13Omi okun ti nrú, ti nhó ifõfó itiju ara wọn jade; alarinkiri irawọ, awọn ti a pa òkunkun biribiri mọ́ dè lailai.
14Awọn wọnyi pẹlu ni Enoku, ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ fun, wipe Kiyesi i, Oluwa mbọ̀ pẹlu ẹgbẹgbãrun awọn enia rẹ̀ mimọ́,
15Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlorun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlorun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlorun ṣe, ati niti gbogbo ọ̀rọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i.
16Awọn wọnyi li awọn ti nkùn, awọn alaroye, ti nrìn nipa ifẹkufẹ ara wọn; ẹnu wọn a mã sọ ọ̀rọ ìhalẹ, nwọn a mã ṣojuṣãjú nitori ere.
Ìkìlọ̀
17Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi;
18Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn.
19Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí.
20Ṣugbọn ẹnyin, olufẹ, ti ẹ ngbe ara nyin ró lori ìgbagbọ́ nyin ti o mọ́ julọ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmí Mimọ́,
21Ẹ mã pa ara nyin mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, ẹ mã reti ãnu Oluwa wa Jesu Kristi titi di iye ainipẹkun.
22Ẹ mã ṣãnu awọn ẹlomiran, ẹ mã fi ìyatọ han:
23Ẹ mã fi ẹ̀ru gba awọn ẹlomiran là, ẹ mã fà wọn yọ kuro ninu iná; ẹ tilẹ mã korira ẹ̀wu tí ara ti sọ di ẽri.
Ibukun
24Njẹ ti ẹniti o le pa nyin mọ́ kuro ninu ikọsẹ, ti o si le mu nyin wá siwaju ogo rẹ̀ lailabuku pẹlu ayọ nla,
25Ti Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo, Olugbala wa, li ogo ati ọlá nla, ijọba ati agbara, nisisiyi ati titi lailai. Amin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jud 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀