Jud 1:17-25

Jud 1:17-25 YBCV

Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi; Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn. Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí. Ṣugbọn ẹnyin, olufẹ, ti ẹ ngbe ara nyin ró lori ìgbagbọ́ nyin ti o mọ́ julọ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmí Mimọ́, Ẹ mã pa ara nyin mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, ẹ mã reti ãnu Oluwa wa Jesu Kristi titi di iye ainipẹkun. Ẹ mã ṣãnu awọn ẹlomiran, ẹ mã fi ìyatọ han: Ẹ mã fi ẹ̀ru gba awọn ẹlomiran là, ẹ mã fà wọn yọ kuro ninu iná; ẹ tilẹ mã korira ẹ̀wu tí ara ti sọ di ẽri. Njẹ ti ẹniti o le pa nyin mọ́ kuro ninu ikọsẹ, ti o si le mu nyin wá siwaju ogo rẹ̀ lailabuku pẹlu ayọ nla, Ti Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo, Olugbala wa, li ogo ati ọlá nla, ijọba ati agbara, nisisiyi ati titi lailai. Amin.