Joṣ 19

19
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Simeoni
1IPÍN keji yọ fun Simeoni, ani fun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn; ilẹ-iní wọn si wà lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Juda.
2Nwọn si ní Beeri-ṣeba, tabi Ṣeba, ati Molada, ni ilẹ-iní wọn;
3Ati Hasari-ṣuali, ati Bala, ati Esemu;
4Ati Eltoladi, ati Bẹtulu, ati Horma;
5Ati Siklagi, ati Beti-markabotu, ati Hasari-susa;
6Ati Beti-lebaotu, ati Ṣaruheni; ilu mẹtala pẹlu ileto wọn:
7Aini, Rimmoni, ati Eteri, ati Aṣani; ilu mẹrin pẹlu ileto wọn:
8Ati gbogbo ileto ti o yi ilu wọnyi ká dé Baalati-beeri, Rama ti Gusù. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn.
9Ninu ipín awọn ọmọ Juda ni awọn ọmọ Simeoni ni ilẹ-iní: nitori ipín awọn ọmọ Juda pọ̀ju fun wọn: nitorina ni awọn ọmọ Simeoni fi ní ilẹ-iní lãrin ilẹ-iní wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Sebuluni
10Ilẹ kẹta yọ fun awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: àla ilẹ-iní wọn si dé Saridi:
11Àla wọn gòke lọ si ìha ìwọ-õrùn, ani titi o fi dé Marala, o si dé Dabaṣeti; o si dé odò ti mbẹ niwaju Jokneamu;
12O si ṣẹri lati Saridi lọ ni ìha ìla-õrùn si ìla-õrùn dé àla Kisloti-tabori; o si yọ si Daberati; o si jade lọ si Jafia;
13Ati lati ibẹ̀ o kọja ni ìha ìla-õrùn si Gati-heferi, dé Ẹti-kasini; o si yọ si Rimmoni titi o fi dé Nea;
14Àla na si yi i ká ni ìha ariwa dé Hannatoni: o si yọ si afonifoji Ifta-eli;
15Ati Katati, ati Nahalali, ati Ṣimroni, ati Idala, ati Beti-lehemu: ilu mejila pẹlu ileto wọn.
16Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Isakari
17Ipín kẹrin yọ fun Issakari, ani fun awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn.
18Àla wọn si dé Jesreeli, ati Kesuloti, ati Ṣunemu;
19Ati Hafaraimu, ati Ṣihoni, ati Anaharati;
20Ati Rabbiti, Kiṣioni, ati Ebesi;
21Ati Remeti, ati Eni-gannimu, ati Enhadda, ati Beti-passesi;
22Àla na si dé Tabori, ati Ṣahasuma, ati Beti-ṣemeṣi; àla wọn yọ si Jordani: ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn.
23Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi ati ileto wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Aṣeri
24Ipín karun yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn.
25Àla wọn si ni Helkati, ati Hali, ati Beteni, ati Akṣafu;
26Ati Allammeleki, ati Amadi, ati Miṣali; o si dé Karmeli ni ìha ìwọ-õrùn, ati Ṣihorilibnati;
27O si ṣẹri lọ si ìha ìla-õrùn dé Beti-dagoni, o si dé Sebuluni, ati afonifoji Ifta-eli ni ìha ariwa dé Betemeki, ati Neieli; o si yọ si Kabulu li apa òsi,
28Ati Ebroni, ati Rehobu, ati Hammoni, ati Kana, ani titi dé Sidoni nla;
29Àla na si ṣẹri lọ si Rama, ati si Tire ilu olodi; àla na si ṣẹri lọ si Hosa; o si yọ si okun ni ìha Aksibu:
30Ati Umma, ati Afeki, ati Rehobu: ilu mejilelogun pẹlu ileto wọn.
31Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Naftali
32Ipín kẹfa yọ fun awọn ọmọ Naftali, ani fun awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn.
33Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Helefu, lati igi-oaku Saanannimu, ati Adami-nekebu, ati Jabneeli dé Lakkumu; o si yọ si Jordani.
34Àla na si ṣẹri lọ sí ìha ìwọ-õrùn si Asnoti-taboru, o si ti ibẹ̀ lọ si Hukkoki; o si dé Sebuluni ni gusù, o si dé Aṣeri ni ìwọ-õrùn, ati Juda ni Jordani ni ìha ìla-õrùn.
35Awọn ilu olodi si ni Siddimu, Seri, ati Hammati, Rakkati, ati Kinnereti;
36Ati Adama, ati Rama, ati Hasoru;
37Ati Kedeṣi, ati Edrei, ati Eni-hasoru;
38Ati Ironi, ati Migdali-eli, Horemu, ati Beti-anati, ati Beti-ṣemeṣi; ilu mọkandilogun pẹlu ileto wọn.
39Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Dani
40Ilẹ keje yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn.
41Àla ilẹ-iní wọn si ni Sora, ati Eṣtaolu, ati Iri-ṣemeṣi;
42Ati Ṣaalabbini, ati Aijaloni, ati Itla;
43Ati Eloni, ati Timna, ati Ekroni;
44Ati Elteke, ati Gibbetoni, ati Baalati;
45Ati Jehudi, ati Bene-beraki, ati Gati-rimmọni;
46Ati Me-jarkoni, ati Rakkoni, pẹlu àla ti mbẹ kọjusi Jọppa.
47Awọn ọmọ Dani si gbọ̀n àla wọn lọ: awọn ọmọ Dani si gòke lọ ibá Leṣemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀, nwọn si pè Leṣemu ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn.
48Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.
Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Kù
49Nwọn si pari pipín ilẹ na fun ilẹ-iní gẹgẹ bi àla rẹ̀; awọn ọmọ Israeli si fi ilẹ-iní kan fun Joṣua ọmọ Nuni lãrin wọn:
50Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA, nwọn fun u ni ilu ti o bère, ani Timnati-sera li òke Efraimu: o si kọ ilu na, o si ngbé inu rẹ̀.
51Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 19: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀