Joṣ 14:6-14

Joṣ 14:6-14 YBCV

Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea. Ẹni ogoji ọdún ni mi nigbati Mose iranṣẹ OLUWA rán mi lati Kadeṣi-barnea lọ ṣamí ilẹ na; mo si mú ìhin fun u wá gẹgẹ bi o ti wà li ọkàn mi. Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o gòke lọ já awọn enia li àiya: ṣugbọn emi tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata. Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, OLUWA da mi si gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdún marunlelogoji yi wá, lati ìgba ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ yi fun Mose, nigbati Israeli nrìn kiri li aginjù: si kiyesi i nisisiyi, emi di ẹni arundilãdọrun ọdún li oni. Sibẹ̀ emi lí agbara li oni gẹgẹ bi mo ti ní li ọjọ́ ti Mose rán mi lọ: gẹgẹ bi agbara mi ti ri nigbana, ani bẹ̃li agbara mi ri nisisiyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wọle. Njẹ nitorina fi òke yi fun mi, eyiti OLUWA wi li ọjọ́ na; nitoriti iwọ gbọ́ li ọjọ́ na bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ̀, ati ilu ti o tobi, ti o si ṣe olodi: bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi. Joṣua si sure fun u; o si fi Hebroni fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní. Nitorina Hebroni di ilẹ-iní Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi titi di oni-oloni; nitoriti o tọ̀ OLUWA Ọlọrun Israeli lẹhin patapata.