Joṣ 14:10-13

Joṣ 14:10-13 YBCV

Njẹ nisisiyi, kiyesi i, OLUWA da mi si gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdún marunlelogoji yi wá, lati ìgba ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ yi fun Mose, nigbati Israeli nrìn kiri li aginjù: si kiyesi i nisisiyi, emi di ẹni arundilãdọrun ọdún li oni. Sibẹ̀ emi lí agbara li oni gẹgẹ bi mo ti ní li ọjọ́ ti Mose rán mi lọ: gẹgẹ bi agbara mi ti ri nigbana, ani bẹ̃li agbara mi ri nisisiyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wọle. Njẹ nitorina fi òke yi fun mi, eyiti OLUWA wi li ọjọ́ na; nitoriti iwọ gbọ́ li ọjọ́ na bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ̀, ati ilu ti o tobi, ti o si ṣe olodi: bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi. Joṣua si sure fun u; o si fi Hebroni fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní.