Joṣ 13

13
Ilẹ̀ Tí Ó kù láti Gbà
1JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.
2Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri;
3Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù:
4Gbogbo ilẹ awọn ara Kenaani, ati Meara ti awọn ara Sidoni, dé Afeki, titi dé àgbegbe awọn Amori:
5Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati:
6Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ.
7Njẹ nitorina pín ilẹ yi ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.
Pípín Agbègbè Tí Ó Wà ní Ìlà Oòrùn Odò Jọrdani
8Pẹlu rẹ̀ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ti gbà ilẹ-iní wọn, ti Mose fi fun wọn ni ìha keji Jordani ni ìha ìla õrùn, bi Mose iranṣẹ OLUWA ti fi fun wọn;
9Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji na, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ Medeba titi dé Diboni;
10Ati gbogbo ilu Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, titi dé àgbegbe awọn ọmọ Ammoni:
11Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka;
12Gbogbo ilẹ ọba Ogu ni Baṣani, ti o jọba ni Aṣtarotu ati ni Edrei, ẹniti o kù ninu awọn Refaimu iyokù: nitori awọn wọnyi ni Mose kọlù, ti o si lé jade.
13Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli kò lé awọn Geṣuri, tabi awọn Maakati jade: ṣugbọn awọn Geṣuri ati awọn Maakati ngbé ãrin awọn ọmọ Israeli titi di oni.
14Kìki ẹ̀ya Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun; ẹbọ OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti a fi iná ṣe ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Reubẹni
15Mose si fi fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni, gẹgẹ bi idile wọn.
16Àla wọn bẹ̀rẹ lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji nì, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ti mbẹ ni ìha Medeba;
17Heṣboni, ati gbogbo ilu rẹ̀ ti mbẹ ni pẹtẹlẹ̀; Diboni, ati Bamoti-baali, ati Beti-baali-meoni;
18Ati Jahasa, ati Kedemoti, ati Mefaati;
19Ati Kiriataimu, ati Sibma, ati Sareti-ṣahari ni òke afonifoji na;
20Ati Beti-peori, ati orisun Pisga, ati Beti-jeṣimotu;
21Ati gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, ti Mose kọlù pẹlu awọn ọmọ alade Midiani, Efi, ati Rekemu, ati Suri, ati Huri, ati Reba, awọn ọmọ alade Sihoni, ti ngbé ilẹ na.
22Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa.
23Ati àla awọn ọmọ Reubeni ni Jordani, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni ilẹ iní awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi idile wọn, awọn ilu ati ileto wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Gadi
24Mose si fi ilẹ fun ẹ̀ya Gadi, ani fun awọn ọmọ Gadi, gẹgẹ bi idile wọn.
25Àla wọn bẹ̀rẹ ni Jaseri, ati gbogbo ilu Gileadi, ati àbọ ilẹ awọn ọmọ Ammoni, titi dé Aroeri ti mbẹ niwaju Rabba;
26Ati lati Heṣboni titi dé Ramatu-mispe, ati Betonimu; ati lati Mahanaimu titi dé àgbegbe Debiri;
27Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn.
28Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọn ati ileto wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Manase ní ìlà Oòrùn
29Mose si fi ilẹ-iní fun àbọ ẹ̀ya Manasse: o si jẹ́ ti àbọ ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse gẹgẹ bi idile wọn.
30Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Mahanaimu lọ, gbogbo Baṣani, gbogbo ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ilu Jairi, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu:
31Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn.
32Wọnyi li awọn ilẹ-iní na ti Mose pín ni iní ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, li apa keji Jordani, lẹba Jeriko ni ìha ìla-õrùn.
33Ṣugbọn ẹ̀ya Lefi ni Mose kò fi ilẹ-iní fun: OLUWA, Ọlọrun Israeli, ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀