NIGBANA ni Jona gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ̀ lati inu ẹja na wá, O si wipe, Emi kigbe nitori ipọnju mi si Oluwa, on si gbohùn mi; mo kigbe lati inu ipo-okú, iwọ si ti gbohùn mi. Nitoriti iwọ ti sọ mi sinu ibu, larin okun; iṣàn omi si yi mi kakiri; gbogbo bibì omi ati riru omi rẹ kọja lori mi. Nigbana ni mo wipe, A ta mi nù kuro niwaju rẹ; ṣugbọn sibẹ emi o tun ma wo iha tempili mimọ́ rẹ. Omi yi mi kakiri, ani titi de ọkàn; ibu yi mi kakiri, a fi koriko-odò wé mi lori. Emi sọkalẹ lọ si isalẹ awọn oke nla; ilẹ aiye pẹlu idenà rẹ̀ wà yi mi ka titi: ṣugbọn iwọ ti mu ẹmi mi wá soke lati inu ibú wá, Oluwa Ọlọrun mi. Nigbati o rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi si wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ́ rẹ. Awọn ti nkiyesi eke asan kọ̀ ãnu ara wọn silẹ. Ṣugbọn emi o fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi o san ẹjẹ́ ti mo ti jẹ. Ti Oluwa ni igbala. Oluwa si sọ fun ẹja na, o si pọ̀ Jona sori ilẹ gbigbẹ.
Kà Jon 2
Feti si Jon 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jon 2:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò