Ṣugbọn Oluwa rán ẹfufu nla jade si oju okun, ijì lile si wà ninu okun, tobẹ̃ ti ọkọ̀ na dabi ẹnipe yio fọ. Nigbana ni awọn atukọ̀ bẹ̀ru, olukuluku si kigbe si ọlọrun rẹ̀, nwọn ko ẹrù ti o wà ninu ọkọ dà sinu okun, lati mu u fẹrẹ. Ṣugbọn Jona sọkalẹ lọ si ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀; o si dubulẹ sùn wọra. Bẹ̃li olori-ọkọ̀ tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ rò, iwọ olõrun? dide, kepe Ọlọrun rẹ, boya Ọlọrun yio ro tiwa, ki awa ki o má bà ṣegbé.
Kà Jon 1
Feti si Jon 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jon 1:4-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò