Joel 3
3
OLUWA Yóo Ṣe Ìdájọ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè
1NITORINA kiyesi i, li ọjọ wọnni, ati li akokò na, nigbati emi o tun mu igbèkun Juda ati Jerusalemu padà bọ̀.
2Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi.
3Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.
4Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
5Nitoriti ẹnyin ti mu fàdakà mi ati wurà mi, ẹnyin si ti mu ohun rere daradara mi lọ sinu tempili nyin:
6Ati awọn ọmọ Juda, ati awọn ọmọ Jerusalemu li ẹnyin ti tà fun awọn ara Griki, ki ẹnyin ba le sìn wọn jina kuro li agbègbe wọn.
7Kiyesi i, emi o gbe wọn dide kuro nibiti ẹnyin ti tà wọn si, emi o si san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
8Emi o si tà awọn ọmọkunrin nyin ati awọn ọmọbinrin nyin si ọwọ́ awọn ọmọ Juda, nwọn o si tà wọn fun awọn ara Sabia, fun orilẹ-ède kan ti o jinà rére, nitori Oluwa li o ti sọ ọ.
9Ẹ kede eyi li ãrin awọn keferi; ẹ yà ogun si mimọ́, ẹ ji awọn alagbara, ẹ sunmọ tòsi, ẹ goke wá gbogbo ẹnyin ọkunrin ologun.
10Ẹ fi irin ọkọ́ itulẹ̀ nyin rọ idà, ati dojé nyin rọ ọkọ̀: jẹ ki alailera wi pe, Ara mi le koko.
11Ẹ kó ara nyin jọ, si wá, gbogbo ẹnyin keferi, ẹ si gbá ara nyin jọ yikakiri: nibẹ̀ ni ki o mu awọn alagbara rẹ sọkalẹ, Oluwa.
12Ẹ ji, ẹ si goke wá si afonifojì Jehoṣafati ẹnyin keferi: nitori nibẹ̀ li emi o joko lati ṣe idajọ awọn keferi yikakiri.
13Ẹ tẹ̀ doje bọ̀ ọ, nitori ikore pọ́n: ẹ wá, ẹ sọkalẹ; nitori ifunti kún, nitori awọn ọpọ́n kún rekọja, nitori ìwa-buburu wọn pọ̀.
14Ọ̀pọlọpọ, ọ̀pọlọpọ li afonifojì idajọ, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ ni afonifojì idajọ.
15Õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, ati awọn irawọ̀ yio fà titàn wọn sẹhin.
Ọlọrun Yóo Bukun Àwọn Eniyan Rẹ̀
16Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli.
17Bẹ̃li ẹnyin o mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ́ mi: nigbana ni Jerusalemu yio jẹ mimọ́, awọn alejo kì yio si là a kọja mọ.
18Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu.
19Egipti yio di ahoro, Edomu yio si di aginju ahoro, nitori ìwa ipá si awọn ọmọ Juda, nitoriti nwọn ti ta ẹjẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ ni ilẹ wọn.
20Ṣugbọn Juda yio joko titi lai, ati Jerusalemu lati iran de iran.
21Nitori emi o wẹ̀ ẹjẹ̀ wọn nù, ti emi kò ti wẹ̀nu: nitori Oluwa ngbe Sioni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joel 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.