Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Joeli ọmọ Petueli wá.
Gbọ́ eyi, ẹnyin arugbo, si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ na. Eyi ha wà li ọjọ nyin, tabi li ọjọ awọn baba nyin?
Ẹ sọ ọ fun awọn ọmọ nyin, ati awọn ọmọ nyin fun awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ wọn fun iran miràn.
Eyi ti iru kòkoro kan jẹ kù ni ẽṣú jẹ; ati eyi ti ẽṣú jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ; eyiti kòkoro na si jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ.
Ji, ẹnyin ọmùti, ẹ si sọkun; si hu, gbogbo ẹnyin ọmùti waini, nitori ọti-waini titun; nitoriti a ké e kuro li ẹnu nyin.
Nitori orilẹ-ède kan goke wá si ilẹ mi, o li agbara, kò si ni iye, ehin ẹniti iṣe ehin kiniun, o si ni erìgi abo kiniun.
O ti pa àjara mi run, o si ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọtọ́ mi kuro, o ti bó o jalẹ, o si sọ ọ nù; awọn ẹ̀ka rẹ̀ li a si sọ di funfun.
Ẹ pohùnrére-ẹkun bi wundia ti a fi aṣọ ọ̀fọ dì li àmure, nitori ọkọ igbà ewe rẹ̀.
A ké ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu kuro ni ile Oluwa; awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, ṣọ̀fọ.
Oko di ìgboro, ilẹ nṣọ̀fọ, nitori a fi ọkà ṣòfo: ọti-waini titun gbẹ, ororo mbuṣe.
Ki oju ki o tì nyin, ẹnyin agbẹ̀; ẹ hu, ẹnyin olùtọju àjara, nitori alikamà ati nitori ọkà barli; nitori ikorè oko ṣègbe.
Ajara gbẹ, igi ọ̀pọtọ́ si rọgbẹ; igi pomegranate, igi ọ̀pẹ pẹlu, ati igi appili, gbogbo igi igbo li o rọ: nitoriti ayọ̀ rọgbẹ kuro lọdọ awọn ọmọ enia.
Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin.
Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa,
A! fun ọjọ na, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ, ati bi iparun lati ọwọ́ Olodumare ni yio de.
A kò ha ké onjẹ kuro niwaju oju wa, ayọ̀ ati inu didùn kuro ninu ile Ọlọrun wa?
Irugbìn bajẹ ninu ebè wọn, a sọ aká di ahoro, a wó abà palẹ; nitoriti a mu ọ̀ka rọ.
Awọn ẹranko ti nkerora to! awọn agbo-ẹran dãmu, nitoriti nwọn kò ni papa oko; nitõtọ, a sọ awọn agbo agùtan di ahoro.
Oluwa, si ọ li emi o ké, nitori iná ti run pápa oko tutú aginju, ọwọ́ iná si ti jo gbogbo igi igbẹ.
Awọn ẹranko igbẹ gbé oju soke si ọ pẹlu: nitoriti awọn iṣàn omi gbẹ, iná si ti jó awọn pápa oko aginju run.