Job Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Jobu jẹ́ ìtàn ọkunrin rere kan tí oríṣìíríṣìí ìṣòro dé bá — ó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ ati ohun ìní rẹ̀, oówo burúkú tún dà bò ó. Ẹni tí ó kọ ìwé yìí fi ewì ṣe àgbékalẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pataki láàrin Jobu ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lórí àwọn àjálù tí ó dé bá Jobu. Àjọṣe láàrin Ọlọrun ati àwọn eniyan ni kókó tí wọ́n tẹnumọ́ jù ninu ọ̀rọ̀ wọn; níkẹyìn Ọlọrun fara han Jobu.
Àwọn ọ̀rẹ́ Jobu fi ojú ìdájọ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wo àjálù tí ó dé bá Jobu. Igbagbọ tiwọn ni pé Ọlọrun a máa san ẹ̀san ohun tí eniyan bá ṣe fún un, ìbáà jẹ́ burúkú tabi ire, ati pé àjálù tí ó dé bá Jobu gbọdọ̀ jẹ́ ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ní ti Jobu, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀; irú àjálù burúkú yìí kò tọ́ sí i, nítorí ẹni rere ati olódodo eniyan bíi tirẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Pẹlu ẹ̀mí ìgboyà, Jobu béèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ìdí tí ó fi lè jẹ́ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí òun. Ninu gbogbo ìṣòro yìí, Jobu di igbagbọ rẹ̀ mú ṣinṣin, ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí Ọlọrun dá òun láre kí ó sì jẹ́ kí òun gba ògo òun pada gẹ́gẹ́ bí ẹni rere.
Ọlọrun kò dáhùn sí gbogbo ìbéèrè Jobu, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fi ewì sọ títóbi agbára ńlá rẹ̀ ati ọgbọ́n rẹ̀ fún Jobu. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jobu fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbé Ọlọrun ga gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ati ẹni ńlá, ó sì tọrọ ìdáríjì fún gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó fi ibinu sọ.
Ìparí ọ̀rọ̀ náà ni àkọsílẹ̀ bí Jobu ṣe pada bọ̀ sípò rẹ̀ àtijọ́ tí ó tún ní ọrọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Jobu nìkan ni ó mọ̀ dájú pé Ọlọrun tóbi ju bí àwọn eniyan ṣe ń fi ojú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wò ó lọ. Ọlọrun jẹ àwọn ọ̀rẹ́ Jobu níyà nítorí pé wọn kò mọ ìdí ìnira tí ó dé bá Jobu.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí náà
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1—2:13
Jobu ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ 3:1—31:40
a. Ìráhùn Jobu 3:1-26
b. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àkọ́kọ́ 4:1—14:22
d. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ẹlẹẹkeji 15:1—21:34
e. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ẹlẹẹkẹta 22:1—27:23
ẹ. Yiyin ọgbọ́n 28:1-28
f. Ọ̀rọ̀ tí Jobu sọ kẹ́yìn 29:1—31:40
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Elihu sọ 32:1—37:24
Èsì tí OLUWA fún Jobu 38:1—42:6
Ọ̀rọ̀ ìparí 42:7-17

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀