Job 7

7
1NJẸ ija kan kò ha si fun enia lori ilẹ, ọjọ rẹ̀ pẹlu kò dabi ọjọ alagbaṣe?
2Bi ọmọ-ọdọ ti ima kanju bojuwo ojiji, ati bi alagbaṣe ti ima kanju wọ̀na owo iṣẹ rẹ̀.
3Bẹ̃li a mu mi ni oṣoṣu asan, oru idanilagãra ni a si là silẹ fun mi.
4Nigbati mo dubulẹ̀, emi wipe, nigbawo ni emi o dide, ti oru yio si kọja? o si tó fun mi lati yi sihin yi sọhun titi yio fi di afẹmọ́jumọ.
5Kòkoro ati ogulùtu erupẹ li a fi wọ̀ mi li aṣọ, àwọ mi bù, o si di sisun ni.
6Ọjọ mi yara jù ọkọ̀ iwunṣọ lọ, o si di lilò li ainireti.
7A! ranti pe afẹfẹ li ẹmi mi; oju mi kì yio pada ri rere mọ.
8Oju ẹniti o ri mi, kì yio ri mi mọ; oju rẹ tẹ mọra mi, emi kò sí mọ́!
9Bi awọ-sanma ti iparun, ti isi fò lọ, bẹ̃li ẹniti nlọ si ipò-okú, ti kì yio pada wá mọ.
10Kì yio pada sinu ile rẹ̀ mọ, bẹ̃ni ipò rẹ̀ kì yio mọ̀ ọ mọ.
11Nitorina emi kì yio pa ẹnu mi mọ, emi o ma sọ ninu irora ọkàn mi, emi o ma ṣe irahùn ninu kikoro ọkàn mi.
12Emi ama iṣe ejo okun tabi erinmi, ti iwọ fi yàn oluṣọ tì mi?
13Nigbati mo wipe, ibusùn mi yio tù mi lara, itẹ mi yio gbé ẹrù irahùn mi pẹlu.
14Nigbana ni iwọ fi alá da mi niji, iwọ si fi iran oru dẹrubà mi.
15Bẹ̃li ọkàn mi yan isà okú jù aye, ikú jù egungun mi lọ.
16O su mi, emi kò le wà titi: jọwọ mi jẹ, nitoripe asan li ọjọ mi.
17Kili enia ti iwọ o ma kokìki rẹ̀? ati ti iwọ iba fi gbe ọkàn rẹ le e?
18Ati ti iwọ o fi ma wa ibẹ̀ ẹ wò li orowurọ̀, ti iwọ o si ma dán a wò nigbakũgba!
19Yio ti pẹ́ to ki iwọ ki o to fi mi silẹ̀ lọ, ti iwọ o fi jọ mi jẹ titi emi o fi le dá itọ mi mì.
20Emi ti ṣẹ̀, kili emi o ṣe si ọ, iwọ Olùtọju enia? ẽṣe ti iwọ fi fi mi ṣe àmi itasi niwaju rẹ, bẹ̃li emi si di ẹrù-wuwo si ara rẹ?
21Ẽṣe ti iwọ kò si dari irekọja mi jì, ki iwọ ki o si mu aiṣedede mi kuro? njẹ nisisiyi li emi iba sùn ninu erupẹ, iwọ iba si wá mi kiri li owurọ̀, emi ki ba ti si.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 7: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀