Job 41

41
1IWỌ le ifi ìwọ fa Lefiatani [ọni nla] jade, tabi iwọ le imu ahọn rẹ̀ ninu okùn?
2Iwọ le ifi ìwọ bọ̀ ọ ni imu, tabi o le ifi ẹgun lu u li ẹrẹkẹ?
3On o ha jẹ bẹ ẹ̀bẹ lọdọ rẹ li ọ̀pọlọpọ bi, on o ha ba ọ sọ̀rọ pẹlẹ?
4On o ha ba ọ dá majẹmu bi, iwọ o ha ma mu u ṣe iranṣẹ lailai bi?
5Iwọ ha le ba a ṣire bi ẹnipe ẹiyẹ ni, tabi iwọ o dè e fun awọn ọmọbinrin iranṣẹ rẹ?
6Ẹgbẹ awọn apẹja yio ha ma tà a bi, nwọn o ha pin i lãrin awọn oniṣowo?
7Iwọ le isọ awọ rẹ̀ kun fun irin abeti, tabi iwọ o sọ ori rẹ̀ kún fun ẹṣín apẹja.
8Fi ọwọ rẹ le e lara, iwọ o ranti ìja na, iwọ kì yio ṣe bẹ̃ mọ.
9Kiyesi i, abá nipasẹ rẹ̀ ni asan, ni kìki ìri rẹ̀ ara kì yio ha rọ̀ ọ wẹsi?
10Kò si ẹni-alaiya lile ti o le iru u soke; njẹ tali o le duro niwaju rẹ̀?
11Tani o ṣaju ṣe fun mi, ti emi iba fi san fun u? ohunkohun ti mbẹ labẹ ọrun gbogbo ti emi ni.
12Emi kì yio fi ipin ara rẹ̀ pamọ, tabi ipá rẹ̀, tabi ihamọra rẹ̀ ti o li ẹwà.
13Tani yio le iridi oju aṣọ apata rẹ̀, tabi tani o le isunmọ ọ̀na meji ehin rẹ̀.
14Tani o le iṣi ilẹkun iwaju rẹ̀? ayika ehin rẹ̀ ni ìbẹru nla.
15Ipẹ lile ni igberaga rẹ̀, o pade pọ mọtimọti bi ami edidi,
16Ekini fi ara mọ ekeji tobẹ̃ ti afẹfẹ kò le iwọ̀ arin wọn.
17Ekini fi ara mọra ekeji rẹ̀, nwọn lẹmọ pọ̀ ti a kò le iyà wọn.
18Nipa sísin rẹ̀ imọlẹ a mọ́, oju rẹ̀ a si dabi ipénpeju owurọ.
19Lati ẹnu rẹ̀ ni ọwọ́-iná ti ijade wá, ipẹpẹ iná a si ta jade.
20Lati iho-imú rẹ̀ li ẽfin ti ijade wá, bi ẹnipe lati inu ikoko ti a fẹ́ iná ifefe labẹ rẹ̀.
21Ẹmi rẹ̀ tinabọ ẹyin, ọ̀wọ-iná si ti ẹnu rẹ̀ jade.
22Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀.
23Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò.
24Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ.
25Nigbati o ba gbe ara rẹ̀ soke, awọn alagbara a bẹ̀ru, nitori ìbẹru nla, nwọn damu.
26Idà ẹniti o ṣa a kò le iràn a, ọ̀kọ, ẹṣin tabi ọfa.
27O ka irin si bi koriko gbigbẹ, ati idẹ si bi igi hihù.
28Ọfa kò le imu u sá, okuta kànakana lọdọ rẹ̀ dabi akeku koriko.
29O ka ẹṣin si bi akeku idi koriko, o rẹrin si ìmisi ọ̀kọ.
30Okuta mimú mbẹ nisalẹ abẹ rẹ̀, o si tẹ́ ohun mimú ṣonṣo sori ẹrẹ.
31O mu ibu omi hó bi ìkoko, o sọ agbami okun dabi kolobó ìkunra.
32O mu ipa-ọ̀na tàn lẹhin rẹ̀, enia a ma ka ibu si ewú arugbo.
33Lori ilẹ aiye kò si iru rẹ̀, ti a da laini ìbẹru.
34O bojuwo ohun giga gbogbo, o si nikan jasi ọba lori gbogbo awọn ọmọ igberaga.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 41: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀