Ipẹ lile ni igberaga rẹ̀, o pade pọ mọtimọti bi ami edidi, Ekini fi ara mọ ekeji tobẹ̃ ti afẹfẹ kò le iwọ̀ arin wọn. Ekini fi ara mọra ekeji rẹ̀, nwọn lẹmọ pọ̀ ti a kò le iyà wọn. Nipa sísin rẹ̀ imọlẹ a mọ́, oju rẹ̀ a si dabi ipénpeju owurọ. Lati ẹnu rẹ̀ ni ọwọ́-iná ti ijade wá, ipẹpẹ iná a si ta jade. Lati iho-imú rẹ̀ li ẽfin ti ijade wá, bi ẹnipe lati inu ikoko ti a fẹ́ iná ifefe labẹ rẹ̀. Ẹmi rẹ̀ tinabọ ẹyin, ọ̀wọ-iná si ti ẹnu rẹ̀ jade. Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀. Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò. Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ.
Kà Job 41
Feti si Job 41
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 41:15-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò