Job 40

40
1OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe,
2Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn!
3Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe:
4Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi.
5Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́.
6Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe:
7Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́.
8Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo?
9Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on?
10Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ.
11Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ.
12Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn.
13Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ.
14Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la.
15Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu.
16Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀.
17On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.
18Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin.
19On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ.
20Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire.
21O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ.
22Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri.
23Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀.
24Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 40: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀