Job 36

36
1ELIHU si sọ si i lọ wipe,
2Bùn mi laye diẹ, emi o si fi hàn ọ, nitori ọ̀rọ sisọ ni o kù fun Ọlọrun.
3Emi o mu ìmọ mi ti ọ̀na jijin wá, emi o si fi ododo fun Ẹlẹda mi.
4Nitoripe ọ̀rọ mi kì yio ṣeke nitõtọ, ẹniti o pé ni ìmọ wà pẹlu rẹ.
5Kiyesi i, Ọlọrun li agbara, kò si gàn ẹnikẹni, o li agbara ni ipá ati oye.
6On kì ida ẹmi enia buburu sí, ṣugbọn o fi otitọ fun awọn talaka.
7On kì imu oju rẹ̀ kuro lara olododo, ṣugbọn pẹlu awọn ọba ni nwọn wà lori itẹ; ani o fi idi wọn mulẹ lailai, a si gbe wọn lekè.
8Bi a ba si dè wọn ninu àba, ti a si fi okun ipọnju dè wọn,
9Nigbana ni ifi iṣẹ wọn hàn fun wọn, ati irekọja wọn ti nwọn fi gbe ara wọn ga.
10O ṣi wọn leti pẹlu si ọ̀na ẹkọ́, o si paṣẹ ki nwọn ki o pada kuro ninu aiṣedede.
11Bi nwọn ba gbagbọ, ti nwọn si sin i, nwọn o lò ọjọ wọn ninu ìrọra, ati ọdun wọn ninu afẹ́.
12Ṣugbọn bi nwọn kò ba gbagbọ, nwọn o ti ọwọ idà ṣègbe, nwọn a si kú laini oye.
13Ṣugbọn awọn àgabagebe li aiya kó ibinu jọ; nwọn kò kigbe nigbati o ba dè wọn.
14Nigbana ni ọkàn wọn yio kú li ewe, ẹmi wọn a si wà ninu awọn oniwa Sodomu.
15On gba otoṣi ninu ipọnju rẹ̀, a si ṣi wọn li eti ninu inilara.
16Bẹ̃ni pẹlupẹlu o si dẹ̀ ọ lọ lati inu ihagaga si ibi gbõrò, ti kò ni wahala ninu rẹ̀; ati ohun ti a si gbe kalẹ ni tabeli rẹ, a jẹ kiki ọ̀ra.
17Ṣugbọn iwọ kún fun idajọ awọn enia buburu; idajọ ati otitọ di ọ mu.
18Nitori ibinu mbẹ, ṣọra ki titó rẹ ma bà tàn ọ lọ; má si ṣe jẹ ki titobi irapada mu ọ ṣìna.
19Ọrọ̀ rẹ pọ̀ to, ti wahala kì yio fi de ba ọ bi? tabi ipá agbara rẹ?
20Má ṣe ifẹ oru, nigbati a nke awọn orilẹ-ède kuro ni ipo wọn.
21Ma ṣọra ki iwọ ki o má yi ara rẹ pada si asan, nitori eyi ni iwọ ti ṣàyan jù sũru lọ.
22Kiyesi i, Ọlọrun a gbeni ga nipa agbara rẹ̀, tani jẹ olukọni bi on?
23Tali o là ọ̀na-iṣẹ rẹ̀ silẹ fun u, tabi tali o lè wipe, Iwọ ti nṣe aiṣedede?
24Ranti ki iwọ ki o gbe iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti enia ima kọrin si.
25Olukuluku enia a ma ri i, ẹni-ikú a ma wò o li okere.
26Kiyesi i, Ọlọrun tobi, awa kò si mọ̀ bi o ti tobi to! bẹ̃ni a kò le wadi iye ọdun rẹ̀ ri.
27Nitoripe on li o fa ikán omi ojo silẹ, ki nwọn ki o kán bi ojo ni ikuku rẹ̀.
28Ti awọsanma nrọ̀, ti o si nfi sẹ̀ lọpọlọpọ lori enia.
29Pẹlupẹlu ẹnikẹni le imọ̀ itanká awọsanma, tabi ariwo agọ rẹ̀?
30Kiyesi i, o tàn imọlẹ yi ara rẹ̀ ka, o si fi isalẹ omi okun bò ara rẹ̀ mọlẹ.
31Nitoripe nipa wọn ni nṣe idajọ enia, o fun ni li onjẹ li ọ̀pọlọpọ.
32O fi imọlẹ̀ bò ọwọ rẹ̀ mejeji, o si ran a si ẹni olodi.
33Ariwo ãrá rẹ̀ fi i han ni, ọ̀wọ-ẹran pẹlu wipe, O sunmọ etile!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 36: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀