BẸ̃NI awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi dakẹ lati da Jobu lohùn, nitori o ṣe olododo loju ara rẹ̀. Nigbana ni inu bi Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, lati ibatan idile Ramu; o binu si Jobu, nitoriti o da ara rẹ̀ lare kàka ki o da Ọlọrun lare. Inu rẹ̀ si bi si awọn ọ̀rẹ rẹ̀ mẹtẹta, nitoriti nwọn kò ni idahùn, bẹ̃ni nwọn dá Jobu lẹbi. Njẹ Elihu ti duro titi Jobu fi sọ̀rọ tan, nitoriti awọn wọnyi dàgba jù on lọ ni iye ọjọ. Nigbati Elihu ri pe idahùn ọ̀rọ kò si li ẹnu awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, nigbana ni o binu. Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin. Emi wipe, ọjọ-jọjọ ni iba sọ̀rọ, ati ọ̀pọlọpọ ọdun ni iba ma kọ́ni li ọgbọ́n. Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye. Enia nlanla kì iṣe ọlọgbọ́n, bẹ̃ni awọn àgba li oye idajọ kò ye. Nitorina li emi ṣe wipe, ẹ dẹtisilẹ si mi, emi pẹlu yio fi ìmọ mi hàn.
Kà Job 32
Feti si Job 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 32:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò