Job 3

3
Jobu Ráhùn sí Ọlọrun
1LẸHIN eyi ni Jobu yanu o si fi ọjọ ibi rẹ̀ ré.
2Jobu sọ, o si wipe,
3Ki ọjọ ti a bi mi ki o di igbagbe, ati oru nì, ninu eyi ti a wipe; a loyun ọmọkunrin kan.
4Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i.
5Ki òkunkun ati ojiji ikú fi ṣe ti ara wọn: ki awọsanma ki o bà le e, ki iṣúdùdu ọjọ na ki o pa a laiya.
6Ki òkunkun ki o ṣúbo oru na biribiri, ki o má ṣe yọ̀ pẹlu ọjọ ọdun na: ki a má ṣe kà a mọ iye ọjọ oṣù.
7Ki oru na ki o yàgan; ki ohùn ayọ̀ kan ki o má ṣe wọnu rẹ̀ lọ.
8Ki awọn ti ifi ọjọ gegun ki o fi i gegun, ti nwọn muratan lati rú Lefiatani soke.
9Ki irawọ̀ ofẽfe ọjọ rẹ̀ ki o ṣokùnkun; ki o ma wá imọlẹ, ṣugbọn ki o má si, bẹ̃ni ki o má ṣe ri afẹmọjumọ́.
10Nitoriti kò se ilẹkun inu iya mi, bẹ̃ni kó si pa ibinujẹ mọ́ kuro li oju mi.
11Ẽṣe ti emi kò fi kú lati inu wá, tabi ti emi kò fi pin ẹmi nigbati mo ti inu jade wá?
12Ẽṣe ti ẽkun wá pade mi, tabi ọmu ti emi o mu?
13Njẹ! nisisiyi, emi iba ti dubulẹ̀ jẹ, emi a si dakẹ, emi iba ti sùn: njẹ emi iba ti simi!
14Pẹlu awọn ọba ati igbimọ aiye, ti o mọle takete fun ara wọn.
15Tabi pẹlu awọn ọmọ-alade ti o ni wura, ti nwọn si fi fadakà kún inu ile wọn.
16Tabi bi ọlẹ̀ ti a sin, emi kì ba ti si; bi ọmọ iṣẹnu ti kò ri imọlẹ.
17Nibẹ ni ẹni-buburu ṣiwọ iyọnilẹnu, nibẹ ẹni-ãrẹ̀ wà ninu isimi.
18Nibẹ ni awọn ìgbekun simi pọ̀, nwọn kò si gbohùn amunisìn mọ́.
19Ati ewe ati àgba wà nibẹ, ẹru si di omnira kuro lọwọ olowo rẹ̀.
20Nitori kili a ṣe fi imọlẹ fun otoṣi, ati ìye fun ọlọkàn kikoro.
21Ti nwọn duro de ikú, ṣugbọn on kò wá, ti nwọn wàlẹ wá a jù fun iṣura ti a bò mọlẹ pamọ.
22Ẹniti o yọ̀ gidigidi, ti inu wọn si dùn nigbati nwọn ba le wá isa-okú ri.
23Kili a fi imọlẹ fun ẹniti ọ̀na rẹ̀ lumọ si, ti Ọlọrun si sọgba di mọ ká?
24Nitoripe imi-ẹ̀dun mi ṣaju ki nto jẹun, ikerora mi si tú jade bi omi.
25Nitoripe ohún na ti mo bẹ̀ru gidigidi li o de ba mi yi, ẹ̀ru ohun ti mo bà li o si de si mi yi.
26Emi kò wà lailewu rí, bẹ̃li emi kò ni isimi, bẹ̃li emi kò ni ìfaiyabalẹ, asiwá-asibọ̀ iyọnu de.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀