Nitori kili a ṣe fi imọlẹ fun otoṣi, ati ìye fun ọlọkàn kikoro. Ti nwọn duro de ikú, ṣugbọn on kò wá, ti nwọn wàlẹ wá a jù fun iṣura ti a bò mọlẹ pamọ. Ẹniti o yọ̀ gidigidi, ti inu wọn si dùn nigbati nwọn ba le wá isa-okú ri. Kili a fi imọlẹ fun ẹniti ọ̀na rẹ̀ lumọ si, ti Ọlọrun si sọgba di mọ ká? Nitoripe imi-ẹ̀dun mi ṣaju ki nto jẹun, ikerora mi si tú jade bi omi. Nitoripe ohún na ti mo bẹ̀ru gidigidi li o de ba mi yi, ẹ̀ru ohun ti mo bà li o si de si mi yi. Emi kò wà lailewu rí, bẹ̃li emi kò ni isimi, bẹ̃li emi kò ni ìfaiyabalẹ, asiwá-asibọ̀ iyọnu de.
Kà Job 3
Feti si Job 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 3:20-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò