LẸHIN eyi ni Jobu yanu o si fi ọjọ ibi rẹ̀ ré. Jobu sọ, o si wipe, Ki ọjọ ti a bi mi ki o di igbagbe, ati oru nì, ninu eyi ti a wipe; a loyun ọmọkunrin kan. Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i. Ki òkunkun ati ojiji ikú fi ṣe ti ara wọn: ki awọsanma ki o bà le e, ki iṣúdùdu ọjọ na ki o pa a laiya. Ki òkunkun ki o ṣúbo oru na biribiri, ki o má ṣe yọ̀ pẹlu ọjọ ọdun na: ki a má ṣe kà a mọ iye ọjọ oṣù. Ki oru na ki o yàgan; ki ohùn ayọ̀ kan ki o má ṣe wọnu rẹ̀ lọ. Ki awọn ti ifi ọjọ gegun ki o fi i gegun, ti nwọn muratan lati rú Lefiatani soke. Ki irawọ̀ ofẽfe ọjọ rẹ̀ ki o ṣokùnkun; ki o ma wá imọlẹ, ṣugbọn ki o má si, bẹ̃ni ki o má ṣe ri afẹmọjumọ́. Nitoriti kò se ilẹkun inu iya mi, bẹ̃ni kó si pa ibinujẹ mọ́ kuro li oju mi.
Kà Job 3
Feti si Job 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 3:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò