Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye? Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè. Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi. A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀. A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri. Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀. A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ. Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e. Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun. Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi. Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá: Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri. Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!
Kà Job 28
Feti si Job 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 28:12-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò